INEC:Ìròyìn òfégè ní pé ilé ẹjọ pàṣẹ fún wa láti dáwọ àkójọ èsì ìbò Gómìnà Rivers dúró

INEC Chairman Mahmud Yakubu Image copyright INEC Situation room
Àkọlé àwòrán Alaga ajọ eleto idibo Mahmud Yakubu

Ajọ eleto idibo Naijiria ti ni ko si ootọ ninu iroyin to n ja rain-rain pe ile ẹjọ ni ki awọn da akojọ esi idibo Gomina ipinlẹ Rivers duro.

Ọjọ kẹsan oṣu Kẹta ni idibo si ipo Gomina ati ti awọn asoju ile asofin ipinlẹ naa waye nipinlẹ naa.

Iroyin to gbode ni pe ile ẹjọ paṣẹ kan eleyi to ṣegbe fun ẹgbẹ oṣelu African Action Congress,eyi to ni ki Inec da ọwọ kika ati akojọ awọn esi idibo to waye nipinlẹ Rivers.

Iroyin naa tun sọ pe ẹgbẹ oṣelu Labour ati Advance Peoples Democratic Alliance na kowe ẹsun tako Inec ni ile ẹjọ giga lAbuja lori ọrọ naa.

Amọ ṣa agbẹnusọ ajọ eleto idibo Inec Rotimi Oyekanmi sọ fun BBC pe ayederu iroyin lasan ni.

''Rara,rara rara,iroyin ẹlẹjẹ ni,ko si nnkankan to jọ bẹ lati ile ẹjọ nipinlẹ Rivers''

Oyekanmi salaye pe ''loni lo yẹ ki a gbe ilana kalẹ, ki ilẹ oni si to ṣu a o gbe jade''

Àkọlé àwòrán Darudapọ waye nidibo Gomina ati awọn asoju ile asofin nipinlẹ Rivers

Ọrọ yi n waye lẹyin ti ile ẹjọ paṣẹ ki Inec dawọ kika ati akojọ esi idibo ni Bauchi.

Inec ti saaju dawọ kika ati ikede ẹni to jawe olubori ninu idiboipinlẹ Bauchi ki ile ẹjọ to paṣẹ ki wọn da duro.

Amọ ṣa Inec ti kọkọ da kika ati ikede esi idibo duro nipinlẹ Rivers nitori wahala ti o waye nibẹ.