Election 2019 Updates: Atiku n ṣé iranran lórí ìbò 1.6 mílíọ̀nù ni-APC

Agbenuso ẹgbẹ oṣelu APC, Lanre Issa-Onilu Image copyright Lanre Issa-Onilu

Ẹgbẹ oselu All Progressives Congress ti fesi si ọrọ oludije ẹgbẹ oselu Peoples Democrativc Party,PDP Atiku Abubakar to ni ohun fi ibo 1.6 miliọnu sagba Muhammadu Buhari ninu ibo aarẹ.

Lanre Onilu to jẹ akọwe ipolongo ẹgbẹ naa ni ''Atiku n ṣe iranra ni''

Ninu atẹjade kan ti o fi sita lọjọru lorukọ ẹgbẹ,Onilu sọ pe awọn ba Atiku kaanu bi awọn ọmọ Naijiria ti ṣe fi ibo wọn da sẹria fun.

O salaye pe ninu gbogbo awọn awawi ti Atiku kojo ninu iwe ipẹjọ rẹ lori esi ibo aarẹ to ti fidirẹmi,eleyi to sọ pe oju opo Inec le jẹri wsi pe ohun fi ibo1.6 miliọnu ju Buhari lọ jẹ eleyi to panilẹrin julọ.

''Ṣe Dubai lo ti ṣagbelẹrọ ibo1.6 miliọnu ni abi awọn alalufa rẹ lo ta esi ibo yi fun un?''

Onilu ni bi Atiku ti ṣe n tẹnumọ oju opo Inec yi mu ifura lọwọ nitori pe ''o jọ bi ẹ ni wi pe ohun ati ẹgbẹ PDP fẹ fi ọgbọn alumọkọrọyi lu oju opo naa lati ṣe akoba fun''

Bi a ko ba gbagbe,Atiku Abubakar ti sọ lọjọru pe ohun fi ibo miliọnu kan le ẹgbẹta ṣagba Buhari ninu ibo aarẹ ti o si tọ ki Inec kede ohun gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori.