Lagos: Àjọ iwádìí ọrọ̀ ajé àgbáyé, EIU ní Ilu eko wà lára àwọn ìlú tó gbọ̀pọ̀ jùlọ lagbaye

Aworan awọn ile kan ni eti odo nilu Eko Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọ̀pọ̀ olùgbé ìlú Eko ló ń pariwo pé kò rọrùn láti gbé níbẹ̀

Njẹ ẹ mọ pe ipinlẹ Eko wa lara awọn ilu mẹwa ti owo gbigbe e rẹ gba ọpọ julọ lagbaye?

Ajọ iwadi ijinlẹ nipa ọrọ aje lagbaye, Economist Intelligence Unit lo sọ bẹẹ ninu abajade iwadii ijinlẹ kan ti wọn ṣe kaakiri orilẹede agbaye.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÀlàyé rèé lórí ilé kẹ̀ta tó wó l'Eko

Bi o tilẹ jẹ pe ọpọ olugbe ipinlẹ Eko ni ko ni fẹ gba eyi gbọ nitori ohun ti oju wọn n ri lori awọn koko igbayegbadun bii ile gbigbe, ọkọ wiwọ, ohun jijẹ rira ati bẹẹbẹẹ lọ, ṣugbọn ajọ iwadii ọrọ aje agbaye naa ni sibẹsibẹ, gbigbe ni ilu Eko ṣi gba ọpọ ju ọpọ awọn ilu nlanla miran kaakiri agbaye.

Ilu Caracas lorilẹede Venezuela lo gba ipo kini, ti ilu Damascus lorilẹede Syria si tẹlee, ilu Tashkent ni orilẹede Uzbekistan, Almaty ni Kazakhstan ati Bangalore lorilẹede India lo tẹlee ni ipo kẹta, kẹrin ati ikarun ni ṣisẹ n tẹlee.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Àjọ iwádìí ọrọ̀ ajé, EIU ní nǹkan rọrùn ju bí ọ̀pọ̀ ṣe lérò lọ ni ilu Eko

Karachi (Pakistan) ati ilu Eko ni wọn jijs wa ni ipo kẹfa ti Buenos Aires ni Argentina ati Chennai India si tun pin ipo keje. New Delhi (India) lo wa ni ipo kẹjọ.

Ọgọjọ ohun amuyẹ bii ounjẹ, ohun mimu, igbokegbodo ọkọ, owo ina atawọn nnkan miran pẹlu owo ile gbigbe ni awọn ajọ naa gbe yẹwo kaakiri awọn ilu mẹtalelaadoje, (133).

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Awọn ilu mẹtalelaadoje kaakiri agbaye ni ajọ̀ EIU gbe yẹwo

Agbejade naa wa ko ilu Paris lorilẹede France,, Hong kOng ati Singapore sita gẹgẹ bii awọn ilu ti o wọn julọ fun eeyan lati gbe lagbaye.

Zurich (Switzerland), Geneva (Switzerland), Osaka (Japan) , Seoul (South Korea), Copenhagen (Denmark) ati New York lorilẹede Amẹrika wa ni ipo keje ti Tel Aviv (Israel) ati Los Angeles (amẹrika) pẹlu ko gbẹyin laaarin awọn ilu mẹwa akọkọ ti owo ati gbe ibẹ gaara pupọ julọ lagbaye.