Deji Adeyanju vs Charley boy: Charly Boy l'óun kò gbowó, Deji ní ó já òun kulẹ̀

Deji Adeyanju ati Charly Boy Image copyright Instagram/Deji Adeyanju
Àkọlé àwòrán Ọrọ lori ẹgbẹ ''Our Mumu Don Do''

Gbajugbaja ajijagbara ati olorin Charles Oputa ti ọpọ eeyan mọ si Charly Boy ti ṣalaye ohun to ṣẹlẹ gan an fanran ede-ai-yede laarin rẹ ati Deji Adeyanju.

Nigba to ba BBC sọrọ, Charly Boy fidi rẹ mulẹ lootọ l'oun gba owo lọwọ agbẹjọro Festus Kenyamo ti ẹgbẹ APC, ṣugbọn owo iṣẹ ti oun ṣe fun APC nipasẹ Kenyamo ni oun gba lọwọ rẹ.

Charly Boy ṣalaye pe irọ ni iroyin to n tan kalẹ lori ayelujara pe oun gba riba gẹgẹ bi ajafẹtọ ọmọniyan.

Ọgbẹni Oputa ni lati ọjọ to ti pẹ ni ajọṣepọ to dan mọran ti wa laarin oun ati Kenyamo, o ni pe oun ti maa n ba ṣiṣẹ tẹlẹ.

Ṣugbọn Deji Adeyanju ninu ọrọ tiẹ pẹlu BBC sọ pe Charly Boy ja oun kulẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionCharly Boy l'óun kò gbowó

O ni o dun oun pe nigba ti oun wa lẹwọn, awọn ti awọn jọ n ja fẹtọ ọmọniyan le laya lati lọ gbowo lọwọ ijọba

Charly Boy fikun ọrọ rẹ pe oun ko ṣegbe lẹyin ọkankan ninu ẹgbẹ oṣelu APC tabi PDP nitori, ọkan ko gbekan bi owu jango lawọn mejeeji.

O ni oun fun ra oun lo sọ fun Kenyamo pe ko gbeṣẹ f'oun, iṣẹ ọhun naa l'oun si ṣe fun un.

Image copyright Twitter/Charly Boy
Àkọlé àwòrán Ẹgbẹ Our Mumu Don Do

Charly Boy loju opo Twitter rẹ sọ pe 'ti baba ko ba sọrọ, o tumọ si pe baba ni ni tootọọ.

O tẹsiwaju pe oun ati Deji lo mọ ohun to n bii ninu, amọ ṣa oun si fẹran rẹ.

O tun sọ pe owo gọbọi l'oun gba lọwọ Kenyamo fun iṣẹ t'oun ṣe, ṣugbọn owo oogu oju oun lowo.

O ni idi niyii t'oun ko le fi fun ẹnikankan ninu owo ti oun gba lori iṣẹ ọhun.