Ilé ẹjọ́ kéde Ademọla Adeleke gẹ́gẹ́ bíi gómìnà ìpínlẹ̀ Ọṣun

Ìròyìn tó ń tẹ̀ wa lọ́wọ́lọ́wọ́ ní wí pé ilé ilé ẹjọ́ tó ń gbọ́ ẹjọ́ ìdìbò gómìnà ìpínlẹ̀ Ọṣun ti kede oludije fun ẹgbẹ oṣelu PDP, Ademọla Adeleke gẹgẹ bii gomina ti ilu dibo yan ni Ọ̀ṣun.

Ilé ilé ẹjọ́ tó ń gbọ́ ẹjọ́ ìdìbò gómìnà ìpínlẹ̀ Ọṣun ti kede oludije fun ẹgbẹ oṣelu PDP, Ademọla Adeleke gẹgẹ bii gomina ti ilu dibo yan ni Ọ̀ṣun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ile ẹjọ naa ninu idajọ to gbe kalẹ ni ọjọ ẹti, ṣalaye pe atundi ibo to waye lawọn ibudo idibo kan ni ọjọ kẹtadinlọgbọn ko ba ofin mu.

Nigba ti awọn adajọ mẹtẹẹta yoo gbe idajọ wọn kalẹ, meji ninu wọn dajọ pe oludije PDP Ademọla Adeleke ni ẹni ti ilu dibo yan.

Eeyan kan to ku, to jẹ alaga igbimọ naa, Onidajọ Ibrahim Sirajo ni tirẹ dajọ gbe Oyetọla ti ẹgbẹ oṣelu APC lẹyin.

Kini awọn ọtọkulu n sọ?

Image copyright Ademola Adeleke
Àkọlé àwòrán ilé ilé ẹjọ́ kede oludije fun ẹgbẹ oṣelu PDP gẹgẹ bii gomina ti ilu dibo yan ni Ọ̀ṣun

Oludije fun ipo arẹ lẹgbẹ oṣelu PDP, Atiku Abubakar ti ki Adeleke ku oriire idajọ to ṣẹṣẹ gba ni ile ẹjọ.

Atiku ni o fihan pe 'lootọ, ẹka idajọ ni ireti araalu ati olugbeja iṣejọba tiwantiwa."

Bakan naa, gbajugbaja olorin takasufe to tun jẹ mọlẹbi Adeleke ni imọlẹ lo de si ipinlẹ Ọṣun bayii.

O wa ki aburo baba rẹ ku oriire.