Osun tribunal: APC ní ìdájọ́ ilé ẹjọ kò lẹ́sẹ̀ ń lẹ̀, Ó ń gba ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lọ

Gboyega Oyetọla Image copyright Gboyega Oyetola
Àkọlé àwòrán Ninu atẹjade kan ti ẹgbẹ oṣelu naa fi sita ni o ti ṣalaye pe idajọ naa ko ba ofin mu rara

Ijọba ipinlẹ Ọṣun pẹlu ti fi atẹjade sita pe wọn gomina Oyetọla ti gba ile ẹjọ kotẹmilọrun lọ ati pe pẹlu eyi, Oyetọla ṣi ni gomina ipinlẹ Ọṣun.

Atẹjade naa ni eto abo yika ile ijọba ipinlẹ naa ti gbopsn sii lati lee daaboobo dukia ati ẹmi gbogbo.

Ilé ẹjọ́ kéde Ademọla Adeleke gẹ́gẹ́ bíi gómìnà ìpínlẹ̀ Ọṣun

Ademọla Adeleke, Fayoṣe, Atiku sọ̀rọ̀ lórí ìdájọ́ ilé ẹjọ́

Ijọba ipinlẹ Ọṣun wa rọ awọn eeyan ipinlẹ naa lati maa ba iṣẹ oojọ wọn lọ lai da omi alaafia ilu laamu.

APC kẹ̀yìn sí ìdájọ́ ilé ẹjọ, Ó ní ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn ló kan

Ẹwẹ, Ẹgbẹ oṣelu APC ti kede wi pe idajọ ti ile ẹjọ gbe kalẹ, eyi to kede Sẹnetọ Ademọla Adeleke gẹgẹ bii gomina ti ilu dibo yan nipinlẹ Ọṣun, ko ni pẹ jẹ rodo lọ ree mu omi nitori pe awọn n gba ile ẹjọ lọ.

ẹgbẹ oṣelu APC ṣalaye ọrọ yii ninu atẹjade kan ti alukoro ẹgbẹ oṣelu naa ni ipinlẹ Ọṣun, Amofin Kunle Ọyatomi fi sita ni ọjọ ẹti.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOsun Election Results 2018: Adeleke sọ pé PDP yóò gba ipò gómìnà rẹ̀ padà nílé ẹjọ́

Ẹgbẹ oṣelu APC ni awọn ko lee gba idajs naa wọle ati pe ile ẹjọ kotẹmilọrun ni awọn n gba lọ bayii.

Gẹgẹ bii ẹgbẹ oṣelu naa ṣe sọ, 'idajọ ọhun ko lee duro labẹ itanna ofin. Nitori naa, a o pẹjọ kotẹmilọrun lori rẹ.