Supplementary Election: "Ijọba ìbilẹ Nasarawa nílò àfikun ọlọpàá ló jẹ ká fi kún un"

Awọn ọlọpaa Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Supplementary Election: "Ijọba ìbilẹ Nasarawa nílò àfikun ọlọpàá ló jẹ ká fi kún"

Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kano ti tún kó àwọm ọlọpàá míràn lọ si Wọọdu Gama ní ìjọba ìbílẹ̀ Nasarawa láti túbọ mú kí ètò ààbò gbópọn síi.

Agbẹnusọ fun àjọ ọlọpaa ní ìpínlẹ̀ Kano, DSP Abdullahi Haruna lásiko tí àwọn oniroyin ń fi ọ̀rọ̀ waa lẹ́nu wò ní ìpínlẹ̀ Kano.

O ni yíyan àwọn ọlọpaa lọ si agbegbe náà kò ṣẹyìn àbẹwo igbákeji ọgá ọlọpàá Anthony Micheal sí agbegbe náà.

O fí kún pé ìròyìn tó àwọn léti pe ètò ààbò kò gbópọn to ní agbégbè náà, èyí ló mu ki ìgbákeji ọgá àgbà ọlọ́pàá ṣe àbẹwò síbẹ̀.

Gẹ́gẹ́ bi ó ṣe sọ yíyàn àwọn ọlọpaa lọ si bẹ̀ jẹ àfikun àwọn to ti wà níbẹ̀ tẹ́lẹ̀ lójúnà àti mú ki ètò aabo dájú le wa fún ẹmi àti ohun ìní àwọn ènìyàn nibi ìdìbò tó ń lọ lọ́wọ́

Lóri awuyewuye pé wọn mú kọmisọ́na fun iṣẹ́ àkanṣe Muktar Ishiaq, agbẹnusọ ọlọpàá sọ pé irá to jìnà sí òòtọ́ ni àti pé òun kò ti gbọ́ ǹkan to jọ bẹ́ẹ̀.

2019 Supplementary election:PDP ní kí INEC wọ́gi lé àtúndì ìbó Kano nítorí ìwà jàǹdùkú

Àkọlé àwòrán Iṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé ni ìjọba ìbílẹ̀ Dala

Alága ẹgbẹ oṣèlú PDP ní ìpínlẹ̀ Kano, Rabiu Bichi ti ni ó ṣe pàtàkì kí àjọ elétò ìdìbò wọ́gilé àtúndi ìbò tó wáye lọjọ́ sátide, ọjọ kẹtàlélógun, ọdun 2019 nítori àwọn àwọn jàndùkú to fọ́nka ìgbòro ti kò si fún ọ̀pọ̀ láàyè láti dìbò.

Bichi sọ èyí di mímọ̀ lásìkò tó pe àwọn oníròyìn jọ lati sàlàyé pé ti wọn ò bá wọ́gilé ìdìbò náà à jẹ́ wípe ilé ẹjọ ni wọn yóò fipàdé sí nítori gbogbo àwọn ènìyàn Kano ló ti fi han pé ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ni àwọn fẹ́ dìbò fún.

"Ńkan tó ṣẹlẹ̀ ní Kano kìí ṣe ìdìbò rárá sùgbọ́n jàndùkú àti ìpánle ti gbogbo ayé sì ń wo. A rọ àjọ elétò ìdìbò INEC láti wọ́gile ìdìbo náà ti wọn bá wa kọ̀ láti wọ́gile a jẹ́ wípe ilé ẹjọ ni à ó ti gba ẹ̀tọ́ wa"

Akọwé ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress (APC) nípinlẹ̀ náà Ibrahim Sarina sọ pé ọ̀rọ̀ ẹgbẹ́ alátakò lásan ní èyí nítori ní ibi ti òun wà ní ijọba ìbílẹ̀ Takai kò si ǹkan to jọ irú ǹkan bẹ́ẹ̀ bí ìdìbò ṣe ń lọ ni ìrọwọ́rọsẹ̀. "Ijọba ìbílẹ̀ Takai ni mo wà ti gbogbo ǹkan sì ń lọ létòletò, ẹ gbagbé gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ ti ẹgbẹ́ alátako ń sọ

Ní Kano, wàhálà àwọ̀n jàǹdùkù, àìtètèdé òṣìṣẹ́ ìdìbò ń dá àtúndì ìbò dúró

Eto idibo ko tete bẹrẹ ni nnkan bii ida ọgọrin ninu ọgọrun awọn ibudo idibo ti atundi idibo ti yẹ ko waye lọjọ abamẹta.

Ko si idi meji ju wi pe wahala to n bẹ silẹ laaarin awọn janduku oloṣelu pẹlu bi awsn oṣiṣẹ ajọ eleto idibo ṣe tun pẹ de pupọ awọn ibudo idibo naa.

Ni awọn ibudo idibo bii mẹwa ti BBC de, idibo ko tii bẹrẹ rara, ohun ti awọn oludibo si n sọ ni pe nṣe lawọn janduku n le awọn oludibo atawọn aṣoju ẹgbẹ alatako kuro ni ibudo idibo.

Ni agbegbe ibudo idibo Gwamamaja, ṣe ni awọn janduku le awọn aṣoju ẹgbẹ oṣelu yooku danu.

Bakan naa si ni ọmọ ṣe ori ni ibudo idibo miran ni ijọba ibilẹ Dala.

Akoko eto idibo ti bẹrẹ kaakiri awọn ipinlẹ to kan

Eto idibo ti bẹrẹ ni ipinlẹ Kano lawọn agbegbe kan ti ajọ INEC ti ni atundi eto idibo yoo ti waye.

Bakan naa ni idibo ti bẹrẹ ni ipinlẹ Sokoto pẹlu.

Ni kutu owurọ ọjọ abamẹta lawọn oludibo ti tu sita lawọn agbegbe bii ijọba ibilẹ Yalwa ni ipinlẹ Kano lati dibo wọn

Image copyright @AWTambuwal
Àkọlé àwòrán INEC, awọn agbofinro ni eto gbogbo ti to fun ikẹsẹjari atundi ibo naa.

Lẹyin idibo si ipo gominato waye lorilẹede Naijiria ni ọjs kẹsan oṣu kẹta, ọdun 2019, idibo ni awọn ipinlẹ mẹfa kan bii Adamawa, Bauchi, Benue, Kano, Plateau ati Sokotoni ajọ INEC kede gẹgẹ bii eyi ti ko pari.

Amọṣa atundi ibo lawọn ipinlẹ marun ninu awọn ipinlẹ wọnyii yoo waye ni ọjọ abamẹta, ọjọ kẹtalelogun oṣu kẹta.

Ajọ INEC ni ireti wa pe gbogbo ohun to n ja ranyinranyin lori eto idibo lawọn ipinlẹ wọnyii yoo jẹ rodo lọ mumi lọjọ abamẹta.

Laaarin ẹgbẹ oṣelu APC ati PDP ni awọn atundi ibo yii yoo ti waye.

Ni ipinlẹ Sokoto, laaarin Aminu Tambuwal ti ẹgbẹ oṣelu PDP ati Aliyyu Sokoto ni idije naa wa. ṣaaju ọjọ abamẹta, ibo to le ni ẹgbẹrun mẹta lo la wọn laaarin.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAdeleke: Àwọn ará Ẹdẹ bẹ síta pẹ̀lú ìdùnnú lórí ìdájọ́ èsì ìdìbò gómínà Ọṣun

Ni ipinlẹ Bauchi laaarinBala Muhammed ti ẹgbẹ oṣelu PDP ati Gomina Mohammed Abubakar ni ọrs wa nitori ibo to le diẹ ni ẹgbẹrun mẹrin lo la wọn.

Ibo to le ni ẹgbẹrun mọkanlelọgọrin ni gomina Samuel Ortom ti ẹgbẹ oṣelu PDP fi n la Emmanuel Jime ti ẹgbẹ oṣelu APC.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOshisko twins: Ojú wa rí, ṣùgbọ́nÌgbọ́raẹniyé ló ń ràn wá lọ́wọ́

Oju gbogbo yoo tun wa lori ipinlẹ Kano nibi ti gomina Abdullahi Ganduje yoo ti maa waako pẹlu Abba Kabir Yusuf ti ẹgbẹ oṣelu PDP.

Ibo ẹgbẹrun mẹrindinlọgbọn ni Yusuf fi n la Ganduje lọwọyii.

Gomina Simon Lalong tẹgbẹ oṣelu APC ati Jeremiah Useni ni yoo jọ ja du ipo naa. ẹgbẹrun lsna ogoji ati diẹ ni ibo to la wọn laaarin, ibo ẹgbẹrun mọkandinlaadọta si ni wọn n ja a le.