Osun tribunal: Ilé ẹjọ́ sọ Adeleke di gómínà, ṣùgbọ́n kò tó bẹ́ẹ̀ kó kó lọ ilé ìjọba

Ọpọ awọn alatilẹyin Ademola Adeleke to jẹ oludije PDP fun ipo gomina Ipinlẹ Osun ninu idibo to koja ni ipinlẹ naa lo bẹ si ita pẹlu ajọyọ ni ọjọ Ẹti bi ile ẹjọ ṣe ni Ademola Adeleke ni ojulowo gomina.

Ọpọ ni yoo si ro pe, bi ile ẹjọ ṣe kede idajọ yii, ṣe ni Adeleke yoo ko ẹru ti yoo si kọri si ile ijọba ni Oṣogbo lati lọ gba ipo rẹ lọwọ Gboyega Oyetọla ti ẹgbẹ oṣelu APC ti ajọ eleto idibo INEC ti kọkọ kede gẹgẹ bii gomina.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOsun Election Results 2018: Adeleke sọ pé PDP yóò gba ipò gómìnà rẹ̀ padà nílé ẹjọ́

Ki ni òfin èto idibo Naijiria sọ?

Iwe ofin eto idibo Naijiria ti ọdun 2010 (Electoral Act 2010), sọ fun wa ni abala ọgọje (140) ni abẹ ipele kẹta wipe ti ile ẹjọ ba ti sọ wipe ẹni to wa lori aleefa kọ́ ni ojúlowo gomina nitori wipe ko ni iye ibo to pọ́ju, ile ẹjọ naa gbọdọ kede orukọ ẹni to ni idibo to pọju gẹgẹ bii gomina.

Eyi ni oun ti ile ẹjọ ti ṣe lori idibo gomina Osun ninu idajọ to waye ni Abuja ni ọjọ Ẹti.

Ṣugbọn abala ẹtalelogoje (143) iwe ofin naa, sọ wipe, ti ile ẹjọ ba ti ri aridaju wipe oludije to wa lori aleefa kọ́ ni ojulowo gomina, ti ẹni naa ba si lọ ile ẹjọ kotẹmilọrun wipe idajọ ile ẹjọ lori esi idibo naa ko tẹ oun lọrun laarin ọjọ mọkanlelogun (21) ti idajọ naa ti waye, ẹni tí ilé ẹjọ ní kìí ṣe ojúlowo gomina naa kò ní fipo silẹ titi di igba ti ilẹ ẹjọ kotẹmilorun ba to da ẹjọ tirẹ.

Idí rèé ti Oyetola ṣi maa ṣe gomina Osun lọ titi ti ile ẹjọ kotẹmilọrun ba to ṣe idajọ tirẹ. Idajọ ile ẹjọ kotẹmilọrun yii ni yoo si sọ boya Adeleke yoo ko lọ ile ijọba tabi idakeji rẹ.