Funke Dosumu on World TB Day: N kò rí ọmọ mi fún ọdún kan torí ikọ́ fée ti mo ní"

Funke Dosumu on World TB Day: N kò rí ọmọ mi fún ọdún kan torí ikọ́ fée ti mo ní"

"Mi ò lè sùn, jẹun, mò ǹ wúkọ́ ní gbogbo oru, mò ń làágùn..."

Oni yii, tii se ọjọ́ Kẹrìnlélógún oṣù Kẹta ni ajọ isọkan agbaye ya sọtọ gẹgẹ bii ayajọ lati gbogun ti arun ikọ ife.

Idi ree ti BBC Yoruba fi tọ obinrin kan, Funkẹ Dosumu lọ, ẹni to ti ni arun yi ri, amọ́ ti ori ko yọ.

Nigba to n salaye ohun ti oju rẹ ri, Funkẹ ni ohun to dun oun julọ lasiko ti oun wa lori akete arun naa ni pe, oun ko fi oju ri ọmọ oun tii se ọmọ ọdun kan.

O fikun pe, se ni wọn ya oun sọtọ ninu yara kan, lai darapọ mọ ọkọ, ọmọ ati gbogbo ẹbi rẹ lapapọ.

Obinrin naa tẹ siwaju pe, lara apẹẹrẹ ti oun n ri pe oun ni arun ikọ ife ni pe oun n wukọ lemọlemọ, oun kii sun loru tori ikọ wiwu, oun n laagun pupọ, ounjẹ kii wu oun jẹ, ti oun si n ru.

Funkẹ to ye arun ikọ ife la, wa rawọ ẹbẹ sawọn eeyan to ba ti n wukọ lemọlemọ, lati lọ se ayẹwo nile iwosan, tori o lee jẹ arun ikọ ife.

Bakan naa, lo tun rọ awọn eeyan to ni arun ikọ ife lati maa lọ fun itọju deede, ki wọn maa lo oogun ati abẹrẹ wọn bo ti yẹ, ki iwosan lee tete de bawọn, tori ikọ ife kii pa ẹni to ba tọju ara rẹ.