Boko Haram: obìnrin tórí kó yọ ní omi àti ewé ńi òun jẹ nínú igbó

Lear Sharibu Image copyright @elharsh

Obinrin kan ti ori ko yọ lọwọ ikọ agbesunmọmi Boko Haram, ti salaye fun pe inu tubu kan naa ni oun ati Leah Sharibu wa, ti o si wa ni alaafia.

Bẹẹ ba gbagbe, Leah Sharibu ni awujọ agbaye ti n pariwo fun idande rẹ lọwọ ikọ Boko Haram, lẹyin ti wn ji gbe pẹlu awọn akẹkọ ileewe girama kan nilu Dapchi, nipinl Yobe.

Bi o tilẹ jẹ pe Boko Haram tu awn akẹk yoku silẹ, amọ wọn ko fi Leah silẹ, nitori pe o faake kọri lati di ẹlẹsin Islam, ko si kuro ni ọmọlẹyin Kristi.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nigba to n sọ iriri rẹ fun akọroyin Punch, obinrin naa ni osu kẹwa ọdun 2018 to kọja, ni oun fi Leah silẹ ni ahamọ, nigba ti oun sa kuro ni agọ Boko Haram.

O ni Leah ni wolii obinrin ni inu tubu ti Boko Haram fi awọn pamọ si, oun lo maa n gbadura fawọn eeyan yoku, to si tun n sisẹ iwosan lati ipasẹ adura rẹ naa.

Ọbinrin ọhun fikun pe asiko kan tiẹ wa, ti inu n run oun, Leah yii lo gbe ọwọ si inu oun, o gbadura fun oun, ti inu riru naa si lọ.

Image copyright @BokoHaramWatch

Nigba to n sọ bo se de ahamọ Boko Haram, obinrin ẹni ọdun mẹẹdọgbọn naa ni, ọja ni oun wa ni Mubi, nigba ti Boko Haram wa ko awọn si ahamọ, ti wọn si fi tipa tipa sọ oun di ẹlẹsin Islam.

O salaye pe wọn mu oun ati ẹgbọn oun obinrin to ni ọmọ meji, amọ se ni Boko Haram fi ọbẹ la ọfun rẹ, nigba to taku lati di ẹlẹsin Islam, ti wn si fi awọn ọmọ rẹ si ahamọ.

Obinrin to jajabọ naa fikun pe, wọn se igbeyawo tipa fun oun pẹ́lu ọmọ ẹ́gbẹ Boko Haram kan, ti oun si bimọ obinrin kan fun, bẹẹ ni wn yi orukọ oun pada si ti musulumi.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionWorld TB Day: Funkẹ Dosunmu ni ikọ́ ife kìí pani, ta bá lo òògùn rẹ̀ déédé

O ni oun sa kuro ni agọ Boko Hram naa pẹlu ọmọ oun ati awọn obinrin mẹjọ miran, amọ awọn yoku ku sinu igbo nitori aisan ati ebi.

Obinrin ọhun ni ewe ati omi ni oun ati ati ọmọ oun n jẹ ninu igbo fun odidi aadọrun ọjọ, eyiun osu mẹta, ki awọn ologun to ri oun ati ọmọ rẹ he ni abẹ oke kan lẹba ipinlẹ Gombe.