Oluwo: Yóò nira fún ìjọba láti sanwó oṣù tí kò bá sí àtúntò

Oba Abbulrasheed Akanbi, Oluwo ti Iwo Image copyright @ObaEmperortelu

Oluwo ti ilu Iwo nipinlẹ Ọsun, Ọba Abdulrasheed Akanbi ti ke gbajare sita pe ti atunse ko ba ba isẹ ọba nipinlẹ naa, yoo nira fun ijọba lati san owo osu awọn osisẹ to kere julọ, ti i se ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira.

Bakan naa ni oriade ọhun fikun pe awọn osisẹ ọba ni ipinlẹ Ọsun ti pọ lapọju, atunse nla si gbọdọ ba ẹka isẹ ọba nipa gbigbe awọn osisẹ ti ko ba ri isẹ se lọ sawọn ẹka ti isẹ wa fun wọn.

Oluwo ke gbajare bẹẹ nibi eto idije kan fawọn akẹkọ ile ẹkọ girama to waye ni ẹkun idibo iwọ oorun ipinlẹ Ọsun, eyi ti ẹgbẹ alaanu kan se agbatẹru rẹ.

Oluwo ni ipinlẹ Ọsun si n tiraka lọwọ ni, ti ko si dangajia to lati san owo osu to kere julọ tẹlẹ, tii se ẹgbẹrun lọna mejidinlogun naira, eyi to fihan pe omi n bẹ lamu fun wọn, ti yoo si nira lati san owo osu tuntun.

Ọba Akanbi fikun pe ohun ta mọ laa mọ, ohun to daju ni pe ẹni to n singba ko lowo lọwọ, ko si si ọna abayọ lọrun ọpẹ, ayafi tijọba ba wa atunse ati atunso si ẹka isẹ ọba ko lee dangajia si.

"Ipinlẹ Ọsun n se aisan, ko si daju pw gomina yoo lee ri owo osu tuntun san. Ọba alaye ni mi, emi kii se oloselu, o si y ki n lee sọ ootọ ọrọ sita. Isẹ nla ni ti ijba yoo ba ri owo osu tuntun san, ayafi ti atunto ba ba ẹka isẹ ọba."

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionWorld TB Day: Funkẹ Dosunmu ni ikọ́ ife kìí pani, ta bá lo òògùn rẹ̀ déédé

"Bawo ni awakọ mẹrindinlogoji yoo se maa pin ọkọ meji wa? eyi gbọdọ dopin, ki atunto si wa, gbogbo awọn osisẹ ti ko ba ri isẹ se ni kijọba gbe lọ sawọn agbọn ti isẹ pọ si."

Bakan naa ni Ọba Akanbi tun pe fun eto pipa owo wọle labẹle lna to se ara ọtọ , paapa ni ẹka awọn aladani, ko lee rọrun fun ijọba lati ri owo lo.