Árẹ̀wá: Bákan náà ni a kò fẹ́ Atiku torí dúkìá àjọni wà tó fẹ́ tà

Atiku Abubakar Image copyright @Atiku

Akọwe apapọ fun ẹgbẹ apapọ awọn eeyan apa oke ọya, Anthony Sani ti kede idi ti ẹgbẹ naa se kẹyin si oludije fun ipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oselu PDP, Atiku Abubakar.

Akọwe Arẹwa to salaye ọrọ yii fawọn akọroyin , tun fikun pe, ẹgbẹ Arẹwa kede atilẹyin rẹ fun oludije fẹgbẹ oselu APC, aarẹ Muhammadu Buhari lẹyin to ti se agbeyẹwo afojusun ẹgbẹ oselu kọọkan, ileri ohun ti wọn fẹ se se ati bi oludije kọọkan se kun oju osuwọn si.

Sani to gba pe lootọ ni kii se asa ati ise ẹgbẹ Arẹwa lati pọn sẹyin oludije ẹgbẹ oselu kan fikun pe, awọn ti fi iroyin nipa oludije si etigbọ awọn oludibo, ki wọn si se idajọ fun wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni awọn fọwọsi aarẹ Muhammadu Buhari lasiko eto idibo to kọja lai naani awọn aise deede ẹgbẹ oselu APC to n sejọba lọwọ, nitori ilọsiwaju ilẹ Naijiria ni.

O fikun pe, ẹgbẹ arẹwa to sẹyin Buhari ko ba lee rọrun fun lati pada wa se afikun awọn aseyọri to ti se tẹlẹ ni saa akọkọ rẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionWorld TB Day: Funkẹ Dosunmu ni ikọ́ ife kìí pani, ta bá lo òògùn rẹ̀ déédé

Sani ni, ko si ẹgbẹkẹgbẹ tabi ẹnikẹni to wa eekanna mọ ẹgbẹ Arẹwa lọrun lati se atilẹyin fun Buhari amọ awọn aseyọri rẹ, afojusun rẹ ninu ileri ipolongo ibo rẹ ati agbara ti ẹgbẹ oselu kọọkan ni, ni awọn se agbeyẹwo rẹ.

Akọwe ẹgbẹ Arẹwa ni, ẹgbẹ naa kẹyin si oludije fun ipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oselu PDP, Atiku Abubakar, nitori bo se n polongo kiri pe oun yoo se atunto ilẹ yii, ti oun yoo si tun ta awọn dukia ajọni wa kan bii ileesẹ NNPC.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOshisko twins: Ojú wa rí, ṣùgbọ́nÌgbọ́raẹniyé ló ń ràn wá lọ́wọ́

O fikun pe, gbogbo awọn dukia ti wọn ti ta nilẹ Naijiria tẹlẹ ko mu eso rere kan wa, bakan naa si ni eto atunto to n polongo ko nitumọ mọ ni asiko yii, tori pe, atunto ti ba awọn ẹka isejọba wa tẹlẹ bii ẹka eto iselu, ọrọ aje ati ẹkun idibo kọọkan.

Antony Sani ni ohun to ja ju lakoko yii ni akoso to peye nipa awọn ohun alumọni orilẹede yii, to si fi ohun to n waye nipinlẹ Eko se apẹẹrẹ.