Supplementary Elections: Ganduje ní ìbò 1,033,695, tí alátakò rẹ̀ sì ní 1,024,713.

Abdullahi Ganduje Image copyright Twitter/Ganduje
Àkọlé àwòrán Atundi ibo gomina ni ipinlẹ Kano

Gómìnà Abdullahi Ganduje, olùdíje ẹgbẹ́ òṣèlú APC, wọlé fún sáà kejì ní ìpínlẹ̀ Kano lẹ́yìn àtúndì ìbò

Ajọ INEC ti kede Gomina Ganduje nirọlẹ ọjọ Aiku gẹgẹ ẹni to jawe olubori pẹlu ibo 1

Alatako Ganduje to nibo to sun mọ julọ, Abba Yusuf oludije fẹgbẹ oṣelu PDP ni ibo 10,239.

Ọjọ Abamẹta ọjọ kẹtalelogun oṣu kẹta ni atundi idibo ọhun waye nipinlẹ Kano.

Gomina Samuel Ortom wọle fun saa keji ni Benue

Gomina Samuel Ortom, to jẹ oludije ẹgbẹ oṣelu PDP ti wọle fun saa keki gẹgẹ bi gomina ipinlẹ Benue lẹyin atundi ibo gomina nipinlẹ naa.

Image copyright Facebook/Sanuel Ortom
Àkọlé àwòrán Atundi ibo Benue

Ọga ajọ INEC, Sebastain Maimako to kede esi ibo naa ṣalaye pe Ortom ni ibo 434,473 nigba ti oludije ẹgbẹ APC to sun mọ julọ Ọgbẹni Emmanuel Jime ni 345,155.

Ki atundi ibo to waye, Ortom ni ibo 410,576 nigba ti Jime si ni ibo 329,022.

Ibudo idibo mẹrin le lugba ni atundi ibo gomina ti waye ni ijọba ibilẹ mejilelogun nipinlẹ Benue

Bala Mohammed, olùdíje PDP, la gómìnà Bauchi mọ́lẹ̀ nínú àtúndì ìbò

Bala Mohammed ti ẹgbẹ oṣelu PDP lo wọle ninu atundi ibo gomina to waye lọjọ Abamẹta to kọja ni ipinlẹ Buachi.

Alakoso ajọ INEC nipinlẹ ọhun, Ọjọgbọn Kyari Mohammed kede pe, Bala la gomina Ipinlẹ Bauchi lọwọlọwọ Mohammed Abdulahi mọ́lẹ pẹlu ibo ẹgbẹrun mẹfa o le lọdunrun un.

Ibo diẹ le lẹgbẹrun marun un ni gomina Abdulahi to jẹ oludije fẹgbẹ oṣelu APC ni, ninu esi atundi ibo ti wọn kede rẹ.

Image copyright Sen Bala Muhammed

Wayi o, ajọ eleto idibo ko lee tii kede ẹni to jawe olubori ninu ibo gomina nipinlẹ Bauchi bayii nitori ibo ijba ibilẹ Tafawa Balewa to wa nile ẹjọ.

Ileejọ giga ilu Abuja lo pasẹ pe ajọ INEC ko gbọdọ tẹsiwaju pẹlu akojọpọ, ipari ati ikede esi ibo gomina nipinlẹ Bauchi.

Ole ni ẹgbẹrun kan ibo ti Bala Mohammed fi bori atundi ibo gomina ipinlẹ Bauchi.

Tambuwal wọlé fún sáà kejì ní Sokoto

Gómìnà Aminu tambuwal ti ipínlẹ̀ Sokoto ti lewaju ninu àtúndì ìbò gómìná tó wáyé lánàá ọjọ́ Satide.

Pẹ̀lú èsì ìbò náà, Tambuwal ti wọlé padà fún sáà keji, gẹ́gẹ́ bíi gómìnà ìpínlẹ̀ Sokoto.

Image copyright @Tambuwal_2019

T

ambuwal, tó ṣojú ẹgbẹ́ PDP ló ní ìbò 512,002 nínú àpapọ̀ ìbò tí wọn kede rẹ, nigbati alátakò rẹ̀ látinú APC, Ahmada Aliyu ní 511,661.

Ìbò 341 ni Tambuwal fi ju Aliyu lọ ninu esi atundi ibo ti ajọ INEC ka.

Lanlong bori atundi ibo ni Plateau

Wayi o, gomina Lalong ti ipinlẹ Plateau naa ti bori idibo gomina ni ipinlẹ Plateau, lati pada fun saa keji ni ile ijọba ipinlẹ naa.

INEC kede Lalong gẹgẹ bi olubori lẹyin atundi ibo to waye ni ipinlẹ naa ni ọjọ Satide, ọjọ Kẹtalelogun oṣu Kẹta ọdun 2019.

Plateau wa lara awọn ipinlẹ marun un ti atundi ibo gomina ti waye.

Esi idibo lawọn ipinlẹ mẹrin yoku ko tii jade, pẹlu iroyin obitibiti wahala awọn janduku atawọn iṣẹlẹ ipa miran to waye nibẹ.

Image copyright @SimonLalong
Àkọlé àwòrán Oniruuru ẹsun iwa jagidijagan lo n kaakiri bayii lori bi awọn janduku ṣe fi oju awọn oludibo ati oniroyin ri mabo nilu Kano lasiko atundi ibo naa

Lalong ni ibo 595,582 lati gbẹyẹ mọ Ọgagunfẹyinti, Jeremiah Useni ti ẹgbẹ oṣelu PDP, ẹni to ni ibo 546,813.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionWorld TB Day: Funkẹ Dosunmu ni ikọ́ ife kìí pani, ta bá lo òògùn rẹ̀ déédé

Ni ipinlẹ Sokoto, ọrọ ko ri bakan naa o pẹlu oniruuru iwa ipa ti iroyin ṣalaye pe o waye nibẹ.

Amọṣa ajọ INEC yoo tẹsiwaju pẹlu kika esi idibo naa.

Ẹwẹ, ni ipinlẹ Kano eeyan mẹwaa ni iroyin sọ pe ọlọpaa ti ko si ahamọ bayii, fun ẹsun iwa jaduku lasiko idibo naa.