Osun tribunal: Oyetọla ní òun kò bẹ̀rù ìdájọ́ ilé ẹjọ́ lórí èsì ìbò ìpínlẹ̀ Ọṣun

Buhari n fa ọwọ Oyetọla soke Image copyright @OSUN_APC

"Emi o bẹru idajọ yii rara. Gbogbo wa lo da loju pe, a ni ẹjọ to duro daradara, awọn ikọ agbẹjọro wa si ti fi eyi da wa loju. Nitori naa ko si idi kan fun ikayasoke."

Eyi ni ọrọ ti Gomina ipinlẹ Ọṣun, Gboyega Oyetọla sọ fawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC to wa kii ni ile ijọba ipinlẹ naa to wa ni ilu Oṣogbo, lori ti idajọ ti ile ẹjọ gbe kalẹ lori esi idibo ipinlẹ naa to waye loṣu Kẹsan ọdun 2018.

Ni ọjọ ẹti ni ile ẹjọ naa dajọ pe, Ademọla Adeleke ti ẹgbẹ oṣelu PDP lo yẹ ki ajọ eleto idibo, INEC kede gẹgẹ bii gomina dipo Oyetọla; ṣugbọn Oyetọla ti sọ pe, ko si ooyẹ kan to lee yẹ idi oun lori aga gomina ipinlẹ Ọṣun nitori pe, o da oun loju ṣaka pe oun lo bori ibo naa.

"Emi ni mo ṣi n ṣejọba, ko si ile ẹjọ kan to yọ mi nipo" ni ọrọ to tẹnu Gomina Oyetọla jade.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionWorld TB Day: Funkẹ Dosunmu ni ikọ́ ife kìí pani, ta bá lo òògùn rẹ̀ déédé

O ni ẹgbẹ oselu APC ti pinnu lati pe ẹjọ kotẹmilọrun pẹlu afikun pe, o da oun loju pe didun ni ọsan yoo so fun oun ni ile ẹjọ kotẹmilọrun.

Bakan naa lo ṣalaye pe, awọn ọjọgbọn kan ninu imọ ofin ti n jiroro lori idajọ naa ni kete ti ile ẹjọ gbe e kalẹ, ohun ti wọn si sọ n mu ireti wa.

O wa sọ siwaju sii pe, aṣẹ ti jade tọ awọn agbofinro lọ lati wa ni igbaradi lati rii pe, ko si idarudapọ laaarin igboro ati pe ẹnikẹni to ba gbimọran ati da omi alaaafia ilu ru, yoo jẹ iyan rẹ niṣu.