Supplementary Election: Àwọn jàndùkú yìnbọn fún òṣìṣẹ́ Inec, Ọ̀jọ̀gbọ́n Tuluen, ní Benue

Mahmood Yakuba Image copyright Twitter/Mahmood Yakubu
Àkọlé àwòrán Atundi ibo

Ajọ eleto idibo orilẹede Naijiria ti sọ pe, lootọọ ni wọn yinbọn fun oṣiṣẹ rẹ kan, Ọjọgbọn C.D Tuluen ni ijọba ibilẹ Gboko nipinlẹ Benue, lọjọ Abamẹta.

Ọjọgbọn C.D Tuluen ṣe kongẹ awọn agbebọn nigba to n lọ si olu ilu ipinlẹ Benue, tii ṣe Makurdi lọjọ Satide.

Alaga ajọ eleto idibo ilẹ wa lo kede iṣẹlẹ naa loju opo Twitter rẹ lọjọ Aiku.

Inec ni esi idibo ijọba ibilẹ naa wa lọwọ rẹ, nigba ti awọn janduku agbebọn kọlu ọkọ to wa ninu rẹ.

Ajọ INEC ṣalaye pe, Ọjọgbọn Tuluen farapa ninu ikọlu naa, bẹẹ lo si n gba itọju nile iwosan lọwọlọwọ.

Ajọ eleto idibo ni gbogbo oṣiṣẹ oun ni oun ṣeto adotofo fun nitori iru iṣẹlẹ bayii.

INEC fidi rẹ mulẹ pe awọn ti fi iṣẹlẹ naa awọn agbofinro leti, bẹẹ iwadii si n lọ lori rẹ

Ṣaaju akoko yii, ọga INEC nipinlẹ Benue, Ọmọwe Nentawe Yilwatda jẹri si ikọlu naa to ṣẹlẹ loju ọna ilu Gboko si Makurdi.