APC: Wọn kò fún wa láàyè láti dibo nígbà ti ẹ̀ri wà pe ẹgbẹ́ PDP ń díbo ní àìmọye ìgbà

Aminnu Tambuwal Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Aminu Tambuwal to jawé olúbori ńi ìpínll Sokoto

Ẹgbẹ́ òsèlú APC, ẹka ti ìpínlẹ̀ Sokoto ti fi ààké kọ́ri pe àwọn kò faramọ èsì àtúndi ìbò tó wáye lọjọ Sátide, nibi ti Gomina Aminu Tambuwal, oludije ẹgbẹ òṣèlú PDP ti jáwé olúbori.

Lásikò ti ó ń ba àwọn akọroyin sọ̀rọ̀ ní ìpínlẹ̀ Sokoto, agbẹ́nusọ ẹgbẹ́ APC Bello Danchadi sọ pe, irọ́ ni èsì ìdìbò ti àjọ INEC gbé jade nítori pé ètò náà ni kọ́nu-n-kọ́họ ninu lọ́jọ́ Sátide, tí àwọn si ti ń ke gbajare ki ètò ìdìbò tó pari.

O ni ẹgbẹ́ ti sááju ké si àjọ INEC nígbà ti ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ń ṣe èrú ibò lọ́jọ́ sátide.

O fi kun pé, ìyàtọ to wa láàrin èsì ìdìbò ẹni to wọle àtí ẹni to fi ìdi rẹmi kéré gbáà si àwọn to forúkọ silẹ̀ nibi ti àtúndi ìbò ti waye, nítoripe wọn kò fún àwọn ènìyàn míràn láàyè láti dibo nígbà ti ẹ̀ri wà pe àwọn ẹgbẹ́ alátako ń díbo ní àìmọye ìgbà.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Samuel Ortom, ẹgbẹ́ òṣèlú PDP tó jáwe olúbori ní Benue

Bakan náà ní ìpínlẹ̀ Benue, ẹgbẹ́ òṣèlú APC nínú àtẹjade kan to fí síta ní Markudi sàlàye pé, èsì àtúndi ìbò to wáye lọ́jọ́ satide kò ṣe àfihan ìfẹ́ àti ìpinnu ará ìlú.

Atejade ọ̀hun ti Eugene Aliegba tó jẹ akọwe ikọ ìpolngo Jime Ode fọwọ si sàlàyé pé, ilé ẹjọ ni àwọn yóò ti yanju gbogbo ọ̀rọ̀ náà.