Èré Ọṣun: Àtáója ní wọn kò jí ère Ọṣun, ó sì wà níbi tó wà

Èré Ọṣun: Àtáója ní wọn kò jí ère Ọṣun, ó sì wà níbi tó wà

Awuyewuye ti gbode lori ibiti ere Ọsun Osogbo wa, eyi to ti di fanfa laarin awọn Ọlọṣun, oloye ati Ataoja tilu Osogbo, idi ree ti BBC Yoruba fi gba ilu Osogbo lọ lati wadi hulẹhulẹ ọrọ naa.

Gẹgẹ bi baba Ọsun, Oloye Adigun Iyanda, to n setọju ere Ọsun ti figbe ta fun araye, ti iya Ọsun, Oloye Ọṣunkẹmi Ọṣunwẹdẹ, to n bọ Ọsun naa si kin lẹyin, wọn ni Ọba ti ta ere Ọsun silẹ okeere, ki Ọsun to taku si papakọ ofurufu, ti baba Ọsun si lọ gbe nibẹ.

Baba ati iya Ọṣun ni, awọn to ji ere Ọṣun naa fẹṣun kan Ataoja atawọn eeyan miran pe, wọn ti gba owo to le ni miliọnu mẹẹdogun naira lọwọ awọn, awọn yoo si gba owo naa pada, kawọn to gbe ere naa silẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Baba Ọsun ni Ataoja fẹ kawọn maa lu jibiti, ki awọn lee maa ri owo ni, bẹẹ si ni ojulowo ere Ọsun ko si ni Osogbo mọ.

Sugbọn Ataoja tilu Osogbo, Ọba Oyetunji Ọlanipẹkun, lasiko to n fesi lori isẹlẹ yii fun BBC Yoruba, o ni irọ to jinna sootọ ni igbe ti baba ati iya Ọsun fi ta, tori ere Ọsun wa ni aafin sugbọn oun ko gbọdọ fi oju ri.

Bakan naa ni iyalode tilu Osogbo, Oloye Awawu asindẹmade naa kin ọba lẹyin pe, wọn ko ta ere Ọsun amọ bi ọba ṣe le ọmọ iya Ọsun ni aafin lori asemase kan, lo mu ki iya Ọsun naa ko jade laafin.

Amọ Araba tilu Osogbo, Oloye Ifayẹmi Ẹlẹbuibọn ti salaye pe, oun ti gbọ nipa fanfa naa, ti ipade si ti n lọ lati tu isu de isalẹ ikoko lori isẹlẹ yii, tawọn yoo si pari rẹ.

Ẹlẹbuibọn ni bi ọrọ yii ba ja asi ootọ̀ọ, ifasẹyin nla lo lee mu ba ilu Osogbo.