Ìjàmbá iná: Sitofu tó gbaná pàdé ike pẹtiró, ni iná bá sọ

Ina to n jo

Ijamba ina to waye ni agbegbe Mile 12, nijọba ibilẹ Kosọfẹ nipinlẹ Eko, ti sọ eeyan di alainile lori, tawọn eeyan miran si padanu sọọbu ọja wọn.

Isẹlẹ naa to waye lopopona Adebimpe lo sọ ọpọ ile ati ibudo itaja ti wọn fi paanu ati pako kọ di eeru.

Gẹgẹ bi Punch ti wi, obinrin kan ti wọn pe ni iya Dada ni ohun idana sitofu rẹ gbina mọ lọwọ, lo ba sọ si ita, pẹki ni sitoofu naa se alabapade kẹẹgi epo petiroolu ti eeyan kan n gbe kọja lọ, ni ina ba sọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ka to wi, ka to fọ, ọwọja ina ọhun ti tan kaakiri adugbo yii, to si jo ọpọ ile ati sọọbu, ti ina ọhun si jo iya Dada kọja ala, to si wa ni ẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun nile iwosan ijọba to wa ni Gbagada.

Bakan naa ni ẹni to fa kẹẹgi epo pẹtroolu lọwọ fara gbọgbẹ diẹ, ti oun naa si n gba itọju lọwọ nile iwosan.

Nigba ti wọn ka iye ofo to ba wọn, ọkan lara awọn aladugbo naa, Oluwo Alapinni ni awọn eeyan to n ko epo pẹtiroolu pam fun tita lna aitọ lo sokunfa bi ọwọja ina ọhun se di rẹpẹtẹ.

"Gbogbo igbinyanju wa lati ẹyin wa lọdọ awọn ọlọpaa lati pinwọ iwa yii lo ja si pabo nitori pe se ni awọn agbofinro maa n kọju sẹgbẹ nigba ti wọn ba ti gba riba lọwọ wọn.

Ina naa ti jo gbogbo ohun ini wa lọ. Gbogbo ohun ta fi gbogbo ọjọ aye wa sisẹ fun, a ko si lee ko ohunkohun jade, bẹẹ ni emi ati awọn ọmọ mi ko nile lori mọ lati sun. Gbogbo awọn eeyan to si dibọn bii ẹni pe wọn n ran wa lọwọ lati ko awọn ẹru wa jade ki ina maa baa jo wọn, ni wọn tun ja wa lole."

Agbẹnusọ fun ileesẹ Ọlọpa nipinlẹ Eko, Arabinrin Bọla Ajao, fidi isẹlẹ naa mulẹ pẹ́lu afikun pe ọpọ ohun to jona ni wn fi awọn ohun eelo ti kii se ọrẹ ina kọ.