Seyi Makinde: Gbogbo iṣẹ́ àgbàṣe tí Ajimọbi ṣe lẹ́yìn ìbò ní màá gbéyẹ̀wò

Seyi Makinde Image copyright Engr Seyi Makinde

Gomina tri ilu sẹsẹ dibo yan nipìnlẹ Ọyọ, Onimọ ẹrọ Seyi Makinde ko tii sinmi lori ariwo to n pa pe, gomina to wa nipo lọwọ, Abiọla Ajimọbi mọọmọ fẹ gbọn owo ilu gbẹ ni ki oun to gba ọpa asẹ lọwọ rẹ ni osu karun ọdun yii.

Atẹjade kan ti agbẹnusọ Seyi Makinde, Dọtun Oyelade fisita salaye pe, se ni ijọba Ajimọbi n fi iwanwara gbe awọn isẹ agbase kan jade pẹlu ọkẹ aimọye biliọnu naira, to si mu ifura dani.

Seyi Makinde wa leri leka pe gbogbo isẹ agbase ti Ajimọbi ba gbe jade lẹyin idibo gomina to kja ni oun yoo tu isu de isalẹ ikoko wọn ni kete ti oun ba gba ọpa asẹ tan losu karun ọdun yiii.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

"Eyi to ya ni lẹnu julọ ni isẹ agbase towo rẹ to biliọnu lọna ọgbọn naira ti Ajimọbi kede rẹ lẹyin ipade igbimọ alasẹ ijọba to waye lọsẹ lọsẹ to kọja, mu ifura dani, paapa nigba to jẹ pe awọn gbese kan wa nilẹ lati 2011 tijọba Ajimọbi ko san."

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÈré Ọṣun: Àtáója ní wọn kò jí ère Ọṣun, ó sì wà níbi tó wà

Makinde fikun pe awọn osisẹ ti wọn ni ifẹ ilu lọkan, ti ke gbajare tọ oun wa pe, Ajimọbi ti n dete lati ri daju pe ijọba to n bọ ko ni tete ri ẹsẹ walẹ, nipa gbingbọn owo ilu gbẹ.