Abducted Child: Bàbà Aisha ní iléèwé ló ti ń bọ̀ nígbà tó bọ́ sọ́wọ́ ajínigbé lóṣù Kẹta

Ọlọpa kan di Aisha mu Image copyright @PoliceNG

Ileewe ni Aisha ti n bọ nigba to lugbadi awọn eeyan ibi naa lọjọ Kẹrindinlogun osu Kẹta ọdun yii ni adugbo Ibudu nilu Warri, nipinlẹ Delta.

Ni kete tawọn obi Aisha ri pe o ti di awati, ni baba rẹ fi isẹlẹ naa to ileesẹ ọlọpa leti, tawọn onitọun naa si bẹrẹ isẹ lọgan nibamu pẹlu asẹ ọga agba ọlọpa ni orilẹede yii.

Lasiko iwadi wọn lori isẹlẹ yii ni ọwọ sinkun awọn ọlọpa ba afurasi meji kan, ti wọn si doola ẹmi ọmọdebinrin naa lọwọ wọn.

Awọn afurasi ti wọn lo gbe Aisha ni ẹni ọgbọn ọdun kan, Abdullahi Abubakar ati iya rẹ, Jummai Salihu, tii se ẹni ọdun mejilelọgọta, tawọn mejeeji wa latilu Lafia, nipinlẹ Nasarrawa.

Iroyin naa ni Abdullahi lo ji Aisha naa gbe, to si fi pamọ si ọdọ mama rẹ, nigba to n kesi awọn obi Aisha lati wa san owo idande rẹ.

Abdullahi yii la gbọ pe odu rẹ kii se aimọ fun oloko awọn obi Aisha ati Aisha funra rẹ, nitori pe o sunmọ mọlẹbi naa tipẹtipẹ ni.

Image copyright @PoliceNG

Asiko to si n se iranwọ lati mu Aisha fo oju titi lasiko ti ọmọdebinrin naa n pada bọ nile iwe ni Abdullahi ji gbe pamọlaimọ si awọn obi ọmọ naa.

Awọn afurasi mejeeji si ti n ka boroboro fun awọn ọlọ[pa nipa ipa ti ikọọkan wọn ko si ijinigbe Aisha., tileesẹ ọlọpa si tun ti n sa ipa rẹ lati ri awọn eeyan miran, ti wọn ka pe o lọwọ ninu isẹlẹ yii, mu.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÈré Ọṣun: Àtáója ní wọn kò jí ère Ọṣun, ó sì wà níbi tó wà

Nigba to n tẹwọ gba ọmọ rẹ, baba Aisha, fo fayọ, to si n dupẹ lọwọ Ọlọrun ati ileesẹ ọlọpa fun isẹ takuntakun ti wọn se lati se awari ọmọ oun nitori oun ti sọ ireti nu lori rẹ tẹlẹ.

Wayi o, ọga agba ọlọpa ti wa kesi awọn obi lati maa mojuto awọn ọmọ wọn bo se yẹ nitori awọn eeyan to sun mọ awọn ọmọde yii, lo maa n pa wọn lara.Ọmọ ọdun marun kan, Aisha Ibrahim, ni ori ti ko yọ lọwọ awọn ajinigbe to gbe pamọ, to si pade alawore ọlọpaa kan, Bukan-Kwatu nilu Lafia nipinlẹ Adamawa, to gba a silẹ.