Ikú Olumegbon: Ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́ta ló lò lókè èèpẹ̀, kó tó mí kanlẹ̀

Fatai Olumegbon Image copyright Fatai Olumegbon
Àkọlé àwòrán O jade laye ni orilẹede Ghana lọjọ kẹrinlelogun oṣu Kẹta lẹni ọdun mọkandinlọgọta.

Ọkan lara awọn afọbajẹ ilu Eko Oloye Fatai Abiodun Olumegbon, ti jade laye.

Olumegbon jẹ́ àgba oyè ni ilu Eko nigba aye rẹ àti ọkan lara awọn afọbajẹ ilu Eko. Bakan naa lo jẹ oloye to n mojuto agbegbe Ajah ati awọn agbegbe miran to sunmọ.

Iroyin fidirẹmulẹ p,e gbajugbaja oloye naa jade laye ni orilẹede Ghana lọjọ aiku, ọjọ Kẹrinlelogun oṣu Kẹta, lẹni ọdun mọkandinlọgọta.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

A gbọ pe aisan kan, ti wọn ko darukọ, lo gba ẹmi rẹ.

Oloye Olumẹgbọn, tii se ọkan lara awọn afọbajẹ nilu Eko, nii tun se Fatai Olumegbon olori oye Idejo ni aafin ọba Eko to wa ni Iduganran.

Related Topics