#FreeOurGirls: Àwọn ènìyàn n fi nkan kun àwòrán àarẹ Pierre Nkurunziza

@iburundi Image copyright @iburundi

Ọpọlọpọ eniyan lo ti n bu ẹnu ẹtẹ lu aarẹ orilẹede Burundi, Pierre Nkurunziza fun bo ṣe paṣẹ pe ki wọn fi awọn ọmọdebinrin mẹta sẹwọn nitori pe wọn fi nnkan kun aworan rẹ ninu iwe kika wọn.

Awọn eniyan naa to n fi ibinu wọn han pẹlu 'hashtag' #FreeOurGirls, eyi to tumọ si tu awọn ọmọbinrin wa silẹ, ni wọn n fi oriṣiriṣi nkan bi irun'mu, irun obinrin and fila kun awọn aworan rẹ lati ṣatilẹyin fun awọn ọmọbinrin naa.

Ẹsun ti wọn fi kan awọn ọmọ naa gẹgẹ bi ajọ ajafẹtọ ọmọniyan kan, Campaign group Human Rights Watch, ṣe sọ ni pe 'wọn ri olori orilẹede naa fin.'

Awọn ọmọbinrin naa yoo wa l'ẹwọn titi ti ile ẹjọ yoo fi gbọ ẹjọ wọn.

Bakan naa ni ajọ naa sọ pe awọn akẹkọọ meje ni wọn kọkọ fi ofin gbe, ko to o di pe wọn fi awọn mẹẹrin silẹ. Ọmọ ọdun mẹtala kan naa wa lara wọn.

Iroyin sọ pe ọjọ ori awọn ọmọ to wa l'ẹwọn naa ko ti i to ọdun mejidinlogun.

Lọsẹ to kọja ni oludari ajọ HRW ni Central Africa, Lewis Mudge sọ pe ''pẹlu gbogbo iwa ọdaran to n waye ni Burundi, o jẹ ibanujẹ pe awọn awọn ọmọde ni wọ̀n n fi ofin gbe nitori wọn fi nkan kun aworan aarẹ.''

Ẹwọn ọdun maarun ni awọn ọmọbinrin naa yoo fi jura ti ile ẹjọ ba fi le fidi rẹ mulẹ pe wọn jẹbi.

Àwọn afíkun lórí ìròyìn yìí