Olùkọ́ aláàánú: Ìda mẹ́jọ sí mẹ́wàá owó oṣù Peter Tabichi, ló ń fún aláìni

Peter Tabichi Image copyright Varkey Foundation
Àkọlé àwòrán Brother Peter Tabichi ni wọn gbe oriyin fun gẹgẹ bii alaanu olukọ

Olukọ sayẹnsi kan ni abule kan ni orilẹede Kenya, ti a gbọ pe o maa n fi gbogbo owo oṣu rẹ tọrẹ fun awọn ọmọ ile iwe to jẹ alaini, ti gba ami ẹyẹ agbaye kan ti wọn fi fun un ni miliọnu kan dọla.

Peter Tabichi, to jẹ ọkan lara awọn ẹgbẹ ijọ aguda ti a mọ si Francisca order, ni o gba ami ẹyẹ naa to jẹ eyi ti wọn gbe kalẹ fun awọn olukọ to gbayi ju ni agbaye.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ida mẹjọ ninu mẹwaa owo oṣu rẹ ni wọn ni o ya sọtọ lati maa fun awọn ọmọ alaini ni ile iwe Keriko to wa ni abule Pwani ni Nakuru.

Wọn yin Tabichi fun iṣẹ takuntakun rẹ ni ile iwe to wa ni abule kan, ni ibi ti ami ẹyẹ naa ti waye ni Dubai.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÈré Ọṣun: Àtáója ní wọn kò jí ère Ọṣun, ó sì wà níbi tó wà

Olukọ naa to jẹ ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn ni wọn ni o n gbe ọrọ sayẹnsi larugẹ. O ṣalaye nibi ayẹyẹ naa wipe, oun fẹ ki awọn ọmọ ilẹ Afirika to jẹ alaini ni anfani lati di eniyan nla ni ibi iṣẹ wọn.

Ọpọlọpọ awọn ọmọ ile iwe rẹ ni a gbọ wipe, o maa n rin irin bii maili mẹrin ki wọn to de ile iwe.

Àkọlé àwòrán Peter Tabichi ni alaanu to ba ami ẹyẹ