Ìjọba Máli: Ìbọn àti àdá ni wọn fi pa àwọn Fulani náà ni lagbegbe Mopti.

Aworan ọmọkunrin Fulani kan to n fun awọn maalu rẹ lomi mu

Aarẹ orileede Mali Boubacar Keita ti parọ olori awọn oṣiṣẹ ile iṣẹ ologun ati olori awọn ọmọ ileeṣẹ ologun lori ikọlu to mu ẹmi awọn eeyan ẹya Fulani to le ni aadoje lọ.

Igbesẹ yi waye lọjọ kan lẹyin ikọlu to waye lagbegbe Mopti nibi ti awọn ọlọdẹ kan ti yabo abule awọn Fulani.

Ẹwẹ,ijọba ti fofin de awọn ẹgbẹ ọlọdẹ ti wọn ni wọn wa nidi ikọlu naa to mu ẹmi eeyan aadoje le mẹrin lọ .

Lọganjọ ọjọ abamẹta ni awọn agbebọn doyika abule awọn ẹya Fulani kan, ti wọn ni wọn ni ohun ṣe pẹlu awọn agbesunmọmi jihadi.

Ohun ti awọn ọlọdẹ naa sọ ni pe, ijọba ko daabo bo awọn lọwọ awọn agbesunmọmi jihadi naa.

Ikọlu naa waye nigba ti awọn aṣoju ajọ isọkan agbaye n jiroro lati dẹkun iwa janduku.

Ikọ igbimọ aabo ajọ naa kan ṣe ipade pẹlu olootu ijọba Mali, Soumeylou Boubeye Maiga, lori ọrọ idunkoko mọni lati ọwọ awọn ajijagbara laarin gbungbun Mali.

Gẹgẹ bi ohun ti iroyin kan lati ọwọ AFP sọ, ''ibọn ati ada'' ni wọn fi pa awọn eeyan ni Ogossagou lagbegbe Mopti.

Awọn ti ọrọ naa soju wọn sọ fun AFP pe, gbogbo ile to wa ni abule naa ni wọn fẹ jo nina tan.

Olori abule Ouenkoro to sunmọ ibẹ ṣapejuwe iṣẹlẹ naa, gẹgẹ bi ohun to buru pupọ.

Àkọlé àwòrán,

Awọn Fulani a ama da ẹranlati abule kan si imiran

Ikọlu laarin awọn ọlọdẹ ẹya Dogon ati awọn Fulani darandaran a ma ṣaba waye lori lilo omi ati ile fun oko dida.

Awọn Dogon fẹsun kan awọn Fulanis pẹ wọn n padi apo pọ pẹlu awọn alakatakiti Jihadi ti awọn Fulani naa si n sọ pe ile iṣẹ ologun Mali n se iranwọ nnkan ija fun awọn ọlọdẹ Dogon.

Dan Na Ambassagou eleyi to tunmọ si awọn ọlọde to fọkan tan Ọlọrun lorukọ ẹgbẹ ọlọde ti ijọba fofin de gẹgẹbiohun ti ajọ to n ja fun ẹtọ ọmniyan Human Rights Watch sọ.