Collapsed Building: Ẹ̀mí kankan kò bọ́ nínú ilé míràn tó wó ládugbó Kakawa l'Eko

Aworan ile to dawo ni Kakawa
Àkọlé àwòrán Iroyin to tẹwa lọwọ sọ pe ijọbati ti wọgile ile naa fun wiwo

Iṣẹlẹ ile wiwo nilu Eko ti wa fẹ di ohun to peleke lẹnu ọjọ mẹta yi pẹlu bi ile miran ṣe tun dawo nisale Eko.

Adugbo Kakawa ni a tun gbọ pe ile miran ti dawo lọjọ Aje.

Gẹgẹ bi iroyin ti o tẹwa lọwọ ti wi, ko si ẹmi kankan to padanu ninu iṣẹlẹ tuntun yi.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÀlàyé rèé lórí ilé kẹ̀ta tó wó l'Eko

Iṣẹlẹ ile wiwo yii ni yoo jẹ ẹlẹkẹtaa ti yoo waye nilu Eko laarin ọsu kan.

Ko ti daju ohun ti o fa iṣẹlẹ ile wiwo tuntun yii ṣugbọn asoju fun Lagos Island nile asofin ipinlẹ Eko, ọgbẹni Sola Giwa,fidi ọrọ naa mulẹ.

Ninu ohun ti o sọ, o ni ko si ẹmi kankan to padanu ninu iṣẹlẹ naa ati wi pe ijọba ti ṣami si ile naa gẹgẹ bi ọkan lara awọn ile ti wọn fẹ wo.

Lọjọ kẹtala Osu yi ni ile alajamẹrin kan dawo ladugbo Ita Faji nibi ti eeyanogun ti padanu ẹmi wọn.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionẸni to ni ile iwe sare lati doola awọn akẹkọ ni ile wolu

Ko pẹ si igba naa, ni ile miran tun dawo ni adugbo Egerton Square, Oke Arin ni Isale Eko kannna.

Ijọba ipinlẹ Eko lẹyin iṣẹlẹ Ita Faji ti bẹrẹ si ni wo awọn ile ti ko duro daada lati dena ijamba ẹmi ati dukia.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÀwọn aladugbo ibí tí ìjọba Èkó tí n wole sọ èrò ọkàn wọn

Related Topics