Election Tribunal: Ẹ̀rù tó ń ba APC ni wọ́n ṣe kọ̀wé sáwọn ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́

Ami idamọ ẹgbẹ PDP Image copyright @OfficialPDPNig

Ẹgbẹ oselu alatako gboogi nil Naijiria, PDP, ti fesi pada lori bi ẹgbẹ oselu to n sejọba lọwọ, APC se figbe ta, lẹ́yìn tí ẹgbẹ́ PDP jáde láti sọ pé àwọn ní ẹ̀rí tí àwọn gbà láti ojú òpó INEC pé, Atiku Abubakar fi ìbò tó lé ní mílíọ̀nù kan jáwé olúborí.

Akọwe ipolongo fẹgbẹ oselu PDP, Kọla Ọlọgbọndiyan, ninu atẹjade kan to fisita loju opo Twitter ẹgbẹ PDP, lati fesi si gbajare ẹgbẹ APC ni, jinnijinni lo n da bo aarẹ ilẹ wa, Muhammadu Buhari ati ẹgbẹ oselu rẹ, APC, nitori ẹjọ ti awọn Atiku pe lati tako esi ibo to gbe BUhari wọle.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọlọgbọndiyan ni ọpọlọ APC ko mọ ọna odo mọ, lo ba da si awuruju, idi si ree to se n kesi awọn ileesẹ ọtẹlẹmuyẹ DSS ati ọlọpa lati fẹhonu han lori abajade awọn nipa oju opo ajọ INEC naa.

PDP wa rọ Buhari ati ẹgbẹ APC lati sinmi irọ pipa, iwa ibanilorukọjẹ ati ipolongo ẹtan, ki wọn si gbaradi lati koju igbẹjọ to wa nilẹ nipa esi ibo aarẹ to kọja.

O ni awọn ẹru aisedeede to pọ babi niwaju igbimọ olugbẹjọ ibo aarẹ, lo wọ APC ati Buhari lọrun, pẹlu ọpọ ẹri to daju pe wọn se eru ibo ni, idi si ree ti wn se n dọgbọn iwa ibanilorukọ jẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÈré Ọṣun: Àtáója ní wọn kò jí ère Ọṣun, ó sì wà níbi tó wà

"Pẹlu bi APC ati Buhari ti n se yii, o ti foju han pe wọn ko ni ẹri to daju lati gbe kalẹ niwaju igbimọ olugbẹjọ ibo, lati tako PDP to ni wọn se eru ibo aarẹ ni."

"O tiẹ wa yani lẹnu pe Festus Keyamo, tii se agba amofin nilẹ Naijiria, to tun wa lara ikọ agbẹjọro Buhari, yẹ ko nimọ ju bayi lọ, ti ko si yẹ ko maa lọwọ si idi fifi ọwọ bo otitọ loju, eyi to foju han fawọn ọmọ Naijiria pe Atiku Abubakar lo jawe olubori ninu ibo aarẹ to kọja."

Image copyright @OfficialPDPNig

PDP fikun pe ni bayii tawọn ti ri pe Buhari ati ẹgbẹ APC ko ni awijare kankan ti wọn fẹ sọ nile ẹjọ, awọn n rọ wọn lati yọ awọn ọmọ Naijiria nipa fifi tinutinu gbe ọpa asẹ le Atiku lọwọ, eyi tawọn ọmọ Naijiria gbe fun latipasẹ ibo wọn

Ìgbìmọ̀ ìpolongo Buhari kọ̀wé sí IGP, DSS pé PDP gbà ọ̀nà ẹ̀bùrú wọ ojú òpó INEC

Igbimọ ipolongo ibo aarẹ orileede Naijiria Muhammadu Buhari ti kesi ileeṣẹ ọlọpaa ati ile iṣẹ ọtẹlẹmuye,DSS lati ṣe iwadi ẹgbẹ oṣelu PDP lori ẹsun pe wọn fi ọna ẹburu wọ oju opo Inec.

Ninu iwe ẹhonu ti agbẹnusọ igbimọ naa, Festus Keyamo, kọ, wọn ni awọn eeyan kan lati gbPDP fi ọna ojoro wọ oju opo Inec ki wọn ba le gbe esi ibo ayederu wọ ibẹ.

Image copyright @fkeyamo
Àkọlé àwòrán Awọn ọdaran kan lati inu ẹgbẹ PDP gbọna ẹburu wọ oju opo INEC

Wọn fi ọrọ yi sita lẹyin ti ẹgbẹ PDP ti saaju fi iwe ehonu tiwọn naa ṣọwọ si igbimọ to n gbẹjọ ẹhonu to niṣẹ pẹlu idibo aarẹ nibi ti wọn ti ni ''awọn ni ẹri tawọn gba lati oju opo Inec to ṣafihan pe Atiku ri ibo 8,356,732 gba lati fẹyin Muhammadu Buhari to ni ibo 16,741,430 janlẹ.''

Gẹgẹ bi ohun ti Keyamo sọ, wi pe awọn ẹgbẹ PDP le ni anfaani lati gba iroyin loju opo Inec ṣafihan pe awọn ọdaran kan lati inu gbẹ naa ni na alumọkọrọyi lati le fọna ẹburu gbe esi ibo wọle.

O sọ ninu iwe ifẹhonu han naa pe igbe ti ẹgbẹ PDP n pa pe ki aarẹ Buhari buwọlu atunto ofin eto idibo eleyi to fi aye kalẹ fun fifi esi ibo ransẹ pẹlu ẹrọ ayarabiaṣa ko koja wi pe wọn ṣe eru.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionFestus keyamo: Ọ̀rọ̀ Obasanjọ sí Buhari ti di ìrégbè

Keyamo ni PDP ti ṣeto esi ibo ti wọn fẹ gbe wọ oju opo Inec amọ isunsiwaju ọjọ ibo lo kawọn lọwọ ko.

"Ẹ gbọdọ kesi gbogbo awn asaaju ẹgbẹ wọn lati le fi ọrọ wawọn lnu wo,wọn gbodo foju ba ile ẹjọ ẹ si gbọdọ ri pe awọn to ba lọwọ ninuiwa yi jẹ iyan wọn niṣu''

Keyamo kasẹ ọrọ rẹ nilẹ pe lootọ ni pe ẹgbv alatako jẹ ohun to da fun ijọba arawa ṣugbọn eleyi ko gbọdo wa jẹ anfaani lati ma fi wu iwa ojoro.