Bauchi Elections: Gómínà Abubakar ti kí Mohammed oludije PDP to jáwé olú borí

Bala Mohammed Image copyright Bala Mohammed/facebook

Gomina Mohammed Abubakar ti ki Sẹnetọ Bala Mohammed to jẹ oludije fun ipo gomina ipinlẹ Bauchi labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP lẹyin ti ajọ eleto idibo INEC kede pe sẹnetọ naa gẹgẹ bi ẹni to bori ninu idibo gomina ipinlẹ naa.

Mohammed fi ẹyin gomina to wa ni iṣakoso, to tun jẹ oludije fun ẹgbẹ All Progressives Congress, APC, Gomina Muhammed Abubakar janlẹ.

Abubakar ki oludije naa lori atẹ Twitter rẹ, ti o si rọ ọ pe ki o sọp fun awọn alatilẹyin rẹ ki wọn so ewe agbejẹ mọ ọwọ.

Mohammed ni apapọ ibo to le ni ẹẹdẹgbẹta ẹgbẹrun (515,113) ti Gomina Abubakar si ni apapọ ibo to le ni ẹẹdẹgbẹta ẹẹgbẹrun bakanna (500,625).

Ọjọgbọn Kyari Mohammed to jẹ alamojuto eto idibo naa lo kede ẹni to bori lẹyin ti atundi ibo gomina ọhun waye.

Bala Mohammed to bori ti fi igba kan jẹ Minisita fun olu ilu orilẹede Naijiria, Abuja.