Rape: Oluwaseun Osowobi ní Commonwealth fún lámì ẹ̀yẹ ọ̀dọ́ tó pegedé jùlọ ní 2018

Rape: Oluwaseun Osowobi ní Commonwealth fún lámì ẹ̀yẹ ọ̀dọ́ tó pegedé jùlọ ní 2018

Iwa ifipabanilopọ ti di tọrọ fọn kale lawujọ wa, ti ọpọ ọdọbinrin si n lugbadi aṣa buruku yii,

Ọkan lara wọn ni Oluwaseun Osowọbi,ẹni ti wọn fi tipa ba lopọ, amọ ti ko fi se ohun itiju to lee pa mọra.

Lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ, Oluwaseun ni o le lootọ lati jẹ ẹni ti wọn fi tipa ba lopọ, nitori ipa to n ni lara onitọun, ninu ọkan ati ọpọlọ rẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Amọ o ni bi o tilẹ jẹ pe wọn ni ki oun dakẹ nigba tọrọ yii sẹlẹ ni 2011, sugbọn oun ke sita loju opo Twitter, ti oun si da ẹgbẹ kan silẹ lọdun 2013, ti yoo fun awọn to ba lugbadi ifipabanilopọ ni anfaani lati ke sita.

Idi ree ti ajọ Commonwealth fi fun ni ami ẹyẹ ọdọ to pegede julọ lọdun 2018, to Oluwaseun si n rọ awọn obinrin ti wọn ba fi tipa ba lopọ lati maa ke sita, ki wọn ma si fi se osun, fi kinra.

Oluwaseun ni afojusun oun ti oun fi da ajọ STER (Stand To End Rape) silẹ ni lati ri daju pe, asa ifipabanibalopọ ko maa waye ni ojoojumọ mọ ni awujọ wa.