Mutiu Agboke: Ìbanilórúkọjẹ́, ìjínigbé, àti ìdúnkookò mọ́ni la kojú lásìkò ìbò

INEC OYO Image copyright INEC
Àkọlé àwòrán Kọmisana fun ajọ INEC nipinlẹ Ọyọ tun kede pe, Ọjọru ni gomina ti wọn dibo yan ati igbakeji rẹ yoo gba iwe mo yege ibo.

Kọmisọnna fun Ajọ eleto idibo INEC ni ipinlẹ Ọyo, Mutiu Agboke ti ni ọpẹlọpẹ isẹ akin ti awọn osisẹ INEC se, ko ba ma si esi idibo fun eto idibo gomina fun ipinlẹ Ọyọ, nitori ko ba ti lọ ni irọwọrọsẹ.

Agboke lo sọ ọrọ yii lasiko to n gba ami ẹyẹ ‘Akinkanju ninu eto iselu tiwantiwa ti ile isẹ iroyin kan ni ilu Ibadan fun un.

O wi pe ati oun ati awọn osisẹ Ajọ INEC ni ijọba ibilẹ mẹtalelọgbọn to wa ni ipinlẹ naa, lo koju isoro ibanilorukọjẹ, ìjínigbé, àti ìdúnkookò mọ́ni lásìkò ìbò, ti wọn si fẹ rẹ salọ kuro lẹnu idibo naa.

Mutiu Agboke fi kun wi pe, lasiko ti ọrọ naa gbomi mu fun oun, ni oun pe Alaga apapọ fun Ajọ INEC, Ọjọgbọn Mahmood Yakubu wi pe, ki ni ki oun se, ti o si pasẹ fun un lati ka esi idibo naa, ki oun si se oun lori esi naa

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÈré Ọṣun: Àtáója ní wọn kò jí ère Ọṣun, ó sì wà níbi tó wà

Kọmisọnna fun Ajọ eleto idibo INEC ni ipinlẹ Ọyọ naa wa fikun wi pe, Ọjọru ni gomina ti wọn dibo yan ati igbakeji rẹ yoo gba iwe mo yege ibo.