Buhari: Iṣẹ́kíṣẹ́ ni awọn akọ́lé ń ṣe pẹ̀lú ilé tó ń dàwó ní Eko lemọ́lemọ́

Muhammadu Buhari

Aarẹ Muhammadu Buhari ti kilọ wi pe ẹnikẹni to ba ko ile lọna ẹburu yoo foju wina ofin lorilẹede Naijiria.

Aarẹ Buhari se ikilọ yii lasiko ti ẹgbẹ awọn surveyor lorilẹede Naijiria, se abẹwo si ile Aarẹ nilu Abuja.

O ni ariwo ile to n wo ni gbogbo igba, eyi to gbalẹ nipinlẹ Eko ati awọn ilu miran fi han wi pe, isẹkisẹ ni awọn akọle ma n se.

''Ẹmi awọn ọdọ to jẹ ogo orilẹede Naijiria lọla, pẹlu agba ati ọmọde ko gbọdọ sofo mọ nitori awọn akọle ko sisẹ wọn kun oju iwọn.''

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionKidnapped Girl: Iyá Ikimot ní lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ìdààmú àti owó láti wá ọmọ náà, òun sọ ìrètí nù

Aarẹ orilẹede Naijiria naa wa pa a lasẹ fun awọn ẹgbẹ awọn akọle lati ri daju wi pe, wọn kọ ile lọna igbalode to ba ofin mu, lati mu ibugbooro ba ọrọ aje lorilẹede Naijiria.