Ipaniyan: Ẹ̀wọ̀n gbére ni adájọ́ fún ọkùnrin náà pé ó jí olólùfẹ́ rẹ̀ gbé

Chukwudi Onweniwe ati Nifemi Adeyeoye Image copyright Makawai.com

Ilé ẹjọ́ giga kan ni Ipinlẹ Ondo ti da ẹjọ iku fun ọmọkunrin kan, Chukwudi Onweniwe, ti wọn fẹsun kan pe o pa ololufẹ rẹ, Nifemi Adeyeoye.

Ọdun 2017 ni ọwọ ọlọpaa ba Onweniwe lẹyin to pa oloogbe naa, to jẹ ọmọ ile iwe Rufus Giwa Polytechnic to wa ni Owo.

Ilu Ogbese ni wọn ni Onweniwe ti pa ọmọdebinrin naa ni oṣu keji ọdun 2017.

Iroyin fi han wipe, Onweniwe fi tipa gbe Nifẹmi lọ si oko kan ni Ogbese lẹyin ti wọn ni aawọ. Ile ẹjọ ni o fipa ba oloogbe naa lopọ, ko to yin lọrun.

Oṣu karun un ọdun 2017 ni igbẹjọ bẹrẹ lori ọrọ naa ti ile ẹjọ fi ẹsun alabala mẹrin kan ọmọdekunrin naa

Nigba ti ile ẹjọ si ṣe agbeyẹwo gbogbo ẹri, adajọ ni olujẹjọ naa jẹbi mẹta ninu ẹsun mẹrin naa, sugbọn ikọ olupẹjọ ko mu aridaju wa wipe, afẹsunkan naa fipa ba oloogbe naa lo.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionRape: Oluwaseun Osowobi ní Commonwealth fún lámì ẹ̀yẹ ọ̀dọ́ tó pegedé jùlọ ní 2018

Adajọ Samuel Bola sọ wipe, iwadi ti wọn se lara oku oloogbe naa fi han wipe, ọrùn ọmọdebirin naa ti wọ́ ati wipe olujẹjọ naa ti fi nkankan fọ ọ lori.

Adajọ Samuel wa fun Onweniwe ni ẹwọn gbére lóri ẹsun ijinigbe, sugbọn lori ẹsun ipaniyan ati wipe o yin oloogbe naa lọ́rùn, adajọ da olujẹjọ naa lẹjọ iku.

Àwọn ìròyìn tí ẹ lè nífẹ̀ẹ́ sí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÈré Ọṣun: Àtáója ní wọn kò jí ère Ọṣun, ó sì wà níbi tó wà

Related Topics