Tani olóṣèlú tó ṣewọn ọjọ mẹta torí pé o ní orí ààrẹ dàrú

Image copyright AFP/GETTY IMAGES
Àkọlé àwòrán Awọn ọlọpaa ati awọn ẹgbẹ alatako ko ṣeṣẹ maa ba ara wọn wọ iya ija lorileede Zambia

Ọmọ ẹgbẹ alatako kan lorileede Zambia ti sun orun ọjọ mẹta lagọ ọlọpaa tori pe o ni ori aarẹ orileede,Edgar Lungu, ko pe.

Sean Tembo to n dari ẹgbẹ Patriots for Economic Progress (PEP),fi orisirisi ọrọ sita loju opo ayelujara eleyi to fi tọka si pe ọpọlọ aarẹ ko munadoko.

O sọ pe o ṣeeṣe ki aarun ọpọlọ ma damu aarẹ pẹlu iru awọn igbesẹ to gbe eleyi ti ku diẹ kaa to.O yari lati yi ọrọ rẹ pada toun ti pe ẹgbẹ to wa ni ijọba ni ki o da ọrọ na pada.

Ẹ gbọ ohun to sọ nipa aarẹ''a ko ni igbagbo pe ẹni ti ori rẹ pe yoo fi owo ara ilu ra ọkọ baalu fun ara rẹ lasiko ti ko tilẹ le san owo osu oṣiṣẹ ijọba lẹlẹkaa jẹka ijọba''

Agbẹnusọ ọlọpaa Esther Katongo fidi ọrọ naa mulẹ.

Ko jẹ tuntun mọ pe ijọba n mu awọn olori alatako lorileede Zambia ti awọn eeyan si ti n bẹnu atẹ lu bi ko ti ṣe si igbalaye fun titako ijọba.

Image copyright AFP/GETTY IMAGES
Àkọlé àwòrán Olori alatako lorileede Zambia Hakainde Hichilema ki ṣe aimọ fun awọn alaṣẹ nitori bi o ti ṣe n tako ijọba Zambia

Lọdun 2017,awọn ọlọpaa mu gbajugbaja olori alatako kan Hakainde Hichilema lẹyin igba ti wnni o da ọkọ aarẹ lọna.

Lọdun to kọja bakanna awọn ọlọpaa mu Fresher Siwale ti ohun naa jẹ ogunagbongbo alatako fun pe o ni ko daju pe ọmọ Zambia ni aarẹ.