Kano Supplementary Election: Àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú 42 tàpá sí èsì ìbò àtúndì Kano

Aworan Gomina Ganduje ẹgbẹ APC ati akẹgbẹ rẹ lati ẹgbẹ PDP
Àkọlé àwòrán Gómìnà Ganduje ti ẹgbẹ́ APC àti akẹgbẹ́ rẹ̀ láti ẹgbẹ́ PDP

Ẹgbẹ oṣelu mejilelogoji ti tako esi ibo atundi Gomina to waye laipẹ yi nipinlẹ Kano.

Agbarijọpọ awọn ẹgbẹ naa labẹ asia Coalition of United Political Parties (CUPP) ni awọn lodi si esi ibo naa to waye lọjọ kẹtalelogun Osu kẹta.

Alaga ẹgbẹ naa Mohammed Abdullahi Rahi sọ fun awọn akọrọyin ni Kano pe wuruwuru ati iwa janduku lo mu abuku ba eto idibo naa ti ajọ Inec dari.

Gẹgẹ bi ohun to sọ, o ni awọn janduku ri iṣẹ ṣe daada lọjọ naa ti wọn si dun koko mọ awọn oludibo kaakiri awọn agọ idibo.

O ṣalaye pe awọn eeyan pupọ si tun padanu ẹmi wọn ti ibo rira si peleke.

"O daju pe iwa janduku to waye lọjọ kẹsan to ṣokunfa atundiu ibo ko to ti ọjọ kẹtalelogun ti ajọ Inec si ṣebi ẹni pe awọn ko ri nnkankan ti wọn si kede esi ibo naa.

"A tako esi ibo to eyi ti wọn ti kede Abdullahi Umar Ganduje gẹgẹ bi ẹni to wole ipo Gomina nitori aisedede to waye saaju, lasiko ati lẹyin idibo atundi to gbe wọlẹ''

Alaga ẹgbẹ alatako PDP nilu Kano,ọgbẹni Rabiu Bichi sọ fun Inec pe ki wọn wọgile idibo atundi naa nitori iwa janduku ati ailedibo awọn oludibo lọpọ agọ idibo.

Bichi lasiko to n sọrọ pẹlu awọn akọroyin ni ti Inec ko ba wọgile esi ibo naa, awọn yoo gbe ọrọ naa lọ si iwaju ile ẹjọ nitori pe awọn eeyan Kano ti fihan pe PDP lawọn yan laayo.