Kidnapped Girl: Iyá Ikimot ní lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ìdààmú àti owó láti wá ọmọ náà, òun sọ ìrètí nù

Kidnapped Girl: Iyá Ikimot ní lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ìdààmú àti owó láti wá ọmọ náà, òun sọ ìrètí nù

Isẹ Oluwa, awamaridi ni ọrọ ijinigbe ati ipadawale ọmọdebinrin kan, Ikimot jẹ nilu Eko.

Lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ, Ikimot ní kẹ́kẹ́ Marwa ni obinrin kan fi ji oun gbe salọ, nigba ti oun n pada bọ lati ile ẹkọ ni Ebute Mẹta.

O ni obinrin naa ta oun ni ẹgbẹrun lọna ọtalelọdunrun o din mẹwa naira (₦350,000) fun ẹlomiran, Christiana Onuchukwu, to n gbe ni adugbo Fadeyi, to si n fi oun se isẹ agbara ati iya ajẹkudorogbo.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Iya yii lo ta oun nidi kan lati pada wa sile lẹyin ọdun marun ti wọn ti ji oun gbe lọ silẹ ibo.

Ninu ọrọ tiẹ naa, Mama Ikimot salaye pe awọn ọrẹ Ikimot ti wọn dijọ n pada bọ lati ileẹkọ sọ pe, ipanu ‘Cheese ball’ ni obinrin kan fun Ikimot, to fi gbe sinu kẹkẹ Marwa.

O ni oun gba Ikimot wo lẹyin ti iya rẹ ku ni, bẹẹ ni oun gbinyanju lati wa ọmọ naa, toun si ta awọn goolu oun lati wa a, sugbọn oun sọ ireti nu lẹyin ọdun meji, ko to fi ẹsẹ ara rẹ rin pada wale.