World theatre Day: Kosọkọ ní ètò adójútòfò wà fọ́jọ́ alẹ́ àwọn onítíátà

Jide Kosoko Image copyright Jide Kosoko

Isẹ tiata abi ere sise kii se isẹ to see fi ọwọ rọ sẹyin ni awujọ wa nitori pataki rẹ.

Yatọ si pe ere tiata maa n dani laraya, o tun maa n kọni lẹkọ, fun ni loye, to si tun n mu ayipada ba awọn iwa ibajẹ lawujọ wa latipasẹ awọn ohun awokọgbọn to wa ninu rẹ.

Bakan naa ni ere tiata maa n se agbelarugẹ asa, ise, ede ati idaabo bo awọn ohun adayeba wa, eyi ti ko fi ni parun, ti yoo si tun maa fi isẹlẹ nipa awọn ohun to ti waye saaju kọ awọn iran ode iwoyi atawọn to n bọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ni bayii ti oni ọjọ Kẹtadinlọgbọn osu Kẹta jẹ ọjọ ti ajọ isọkan agbaye ya sọtọ gẹgẹ bii ayajọ ọjọ tiata lagbaye, eyi lo mu ki BBC Yoruba maa beere pe se awọn osere tiata Yoruba n pọnmi silẹ de oungbẹ bi fun ọjọ alẹ wọn abi asiko ti ilera yoo beere?

Bakan naa la fẹ mọ awọn eto to wa nilẹ ti ẹgbẹ awọn osere tiata n se lati ri daju pe awọn ọmọ ẹgbẹ wọn ko maa laagun, ki wọn to ri itọju lasiko ti ilera wọn ba yinjẹ?

Image copyright Mr Latin

Nigba to n dahun ibeere yii, agba ọjẹ kan nidi isẹ tiata, to jẹ odu, ti kii se aimọ fun oloko laarin awọn osere tiata, Ọmọọba Jide Kosọkọ ni ẹgbẹ awọn osere ori itage lede Yoruba, taa mọ si TAMPAN, labẹ akoso ọgbẹni Bọlaji Amusan, ti gbogbo eeyan mọ si Mr Latin, ti n se gudugudu meje, ati yaya mẹfa fun eto adojutodo fawọn ọmọ ẹgbẹ naa.

Ẹ gbọ́ Jide Kosọkọ siwaju si:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionWorld theatre Day: Kosọkọ ní ètò adójútòfò wà fọ́jọ́ alẹ́ àwọm onítíátà

Kosọkọ ni amọ irufẹ eto adojutofo yii ko ba ti waye tipẹ fawọn osere tiata Yoruba, bi kii ba se ọpọ wọn to pagi dina eto naa nigba naa, apẹyinda iwa aidaa yii si ni ọpọ wọn to n saisan n jẹ loni yii.

Jide Kosọkọ wa tun rọ awọn ọmọ ẹgbẹ osere tiata lede Yoruba lati maa tọju ara wọn, ki wọn ma si lo gbogbo owo ti wọn n ri lati fi jẹnu tan, amọ ki wọn pọn omi silẹ de oungbẹ fun ọjọ alẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionKidnapped Girl: Iyá Ikimot ní lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ìdààmú àti owó láti wá ọmọ náà, òun sọ ìrètí nù