Ọ̀pọ̀ òṣèré tíátà tó ń sàìsàn ni kò ṣe dáadáa fẹ́gbẹ́ - Jide Kosọkọ
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

World theatre Day: Kosọkọ ní ètò adójútòfò wà fọ́jọ́ alẹ́ àwọm onítíátà

Nigba to n dahun ibeere yii, agba ọjẹ kan nidi isẹ tiata, to jẹ odu, ti kii se aimọ fun oloko laarin awọn osere tiata, Ọmọọba Jide Kosọkọ ni ẹgbẹ awọn osere ori itage lede Yoruba, taa mọ si TAMPAN, labẹ akoso ọgbẹni Bọlaji Amusan, ti gbogbo eeyan mọ si Mr Latin, ti n se gudugudu meje, ati yaya mẹfa fun eto adojutodo fawọn ọmọ ẹgbẹ naa.

Kosọkọ ni amọ irufẹ eto adojutofo yii ko ba ti waye tipẹ fawọn osere tiata Yoruba, bi kii ba se ọpọ wọn to pagi dina eto naa nigba naa, apẹyinda iwa aidaa yii si ni ọpọ wọn to n saisan n jẹ loni yii.

Jide Kosọkọ wa tun rọ awọn ọmọ ẹgbẹ osere tiata lede Yoruba lati maa tọju ara wọn, ki wọn ma si lo gbogbo owo ti wọn n ri lati fi jẹnu tan, amọ ki wọn pọn omi silẹ de oungbẹ fun ọjọ alẹ.