Abiola Ajimobi: Makinde fẹ́ fọwọ́ rọ́ àṣeyọrí ọlọ́dún mẹ́jọ mi sẹ́yìn

Seyi Makinde ati Abiola Ajimobi
Àkọlé àwòrán Seyi Makinde ti ẹgbẹ́ òsèlú PDP ní àwọn ènìyàn dìbò yàn gẹ́gẹ́ bí gómìnà tuntun ní ìpínlẹ̀ Ọyọ.

Gomina ipinlẹ Ọyọ, Abiola Ajimobi ti parọ̀wa si gomina tuntun ti wọn sẹsẹ yan, Seyi Makinde lati sọra fun ọrọ kubakugbe nipa oun ati isejọba ọdun mẹjọ oun.

Ajimobi ninu atẹjade to fi lede ni gbogbo isẹ Makinde lo n fihan wi pe, o fẹ fi ọwọ rọ gbogbo isẹ ti oun ti se fun ọdun mẹjọ ni ipinlẹ Ọyọ.

Ninu ọrọ rẹ, o ni ẹgbẹ oselu PDP yẹ ki wọn bẹrẹ si ni sọ ohun ti wọn ni fun awọn eniyan, ati lati mọ le akasọ lori awọn ipinlẹ ti oun ti fi silẹ gẹgẹ bi isẹ ti oun ti se.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionKidnapped Girl: Iyá Ikimot ní lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ìdààmú àti owó láti wá ọmọ náà, òun sọ ìrètí nù

O ni ohun to buru jai ni lati ma a lo ẹrọ ayelujara lati fi tabuku oun lawujọ.

Gomina ipinlẹ Ọyọ naa wa parọwa fun wọn lati dawo gbogbo ise yii ku, ki ipinlẹ Ọyọ le tẹsiwaju.