Ondo: Ọ̀rẹ́kùnrin Khadijat Olubọyo gba ọjọ́ ikú!

Khadijat Oluboyo
Àkọlé àwòrán Ọ̀rẹ́kùnrin Khadijat Olubọyo gba ọjọ́ ikú

Ile ẹjọ giga ni ipinlẹ Ondo ti da ẹjọ iku fun Seidu Adeyemi to pa ọmọ igbakeji gomina ipinlẹ Ondo, Khadijat Olubọyọ ní ọdun to kọja.

Seidu Adeyemi to jẹ ọrẹkunrin Khadijat Oluboyo ni wọn fẹsun kan wi pe o pa a, ti o si tun riimọle si inu yara rẹ ni Aratusi, Oke-Aro ni Akure, nipinlẹ Ondo.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionKhadijat Oluboyo: Ilé ẹjọ́ sọ ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ sí gbaga

Khadijat Oluboyo n mura lati jade fasiti ni ile iwe giga fasiti Adekunle Ajasin ni Akungba Akoko ni ipinlẹ Ondo ki o to jade laye

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBaba Khadijat Oluboyo jẹ́rìí ọmọ rẹ̀