Àwọn wo ló kó oníkẹ̀ẹ̀kẹ́ 'Napep' wọ ìgboro ìlú Liverpool?

Awọn kẹkẹ NAPEP Image copyright @LoksattaLive
Àkọlé àwòrán Awọn kẹẹkẹ naa jẹ ọna irinna to yatọ si eleyi to ti wa nilẹ tẹlẹ bi Uber

Bi ẹ ba laanfaani lati lọ si ilu ọba, ẹ ri wi pe ẹ foju sita boya ẹ o ṣe alabapade 'Kẹẹkẹ Napep' iru eleyi ti o n gbe ero lawọn ilu kaakiri Naijiria.

Bẹẹni, 'Kẹkẹ Napep' ti n na igboro ilu Liverpool nilu Ọba.

Ọrọ yi di ootọ pẹlu bi ile iṣe ọlọkọ irina kan ti ṣe ṣe ifilọlẹ ọkọ akero 'Kẹẹkẹ Napep' fun awọn eeyan ilu Liverpool nilẹ Gẹẹsi.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionGrandma Maruwa: Ó yẹ kí obìnrin sisẹ́ láì wojú ọkọ kó tó jẹun

Ko si ohun ti awọn kẹẹkẹ wọn yi fi yatọ si eyi ti awọn eeyan ma n wọ ni Naijiria, bi ko ṣe pe awọ ewe ni wọn kun awọn ọkọ naa.

Gẹgẹ bi ohun ti a ri ka, ile isẹ to bẹrẹ eto yi salalye pe awọn gbe awọn kẹẹkẹ naa kalẹ ki awọn ara ilu ba le mọ riri eto irina orisi miran yatọ si eleyi ti wọn n lo tẹlẹ.

Yatọ si orileede Naijiria,pupọ awọn orileede nilẹ Asia bi India,Bangladesh ati Singapore lawọn eeyan ti ma n wọ kẹẹkẹ ẹlẹsẹmẹta yii.

Awọn eeyan orilẹede India ni wọn kọkọ bẹrẹ si ni lo awọn ọkọ to jọ bi 'kẹẹkẹ Napep' fun awọn to n ṣe inaju ati igbafẹ.

Image copyright Getty Images

Ilu London wa lara awọn ilu ti kẹẹkẹ yi ti kọkọ gbalẹ gẹgẹ bi ohun irinna.

Awọn ọkọ yi jẹ ohun irinna pọọkulowo, ṣugbọn ipenija aabo jẹ iṣoro kan ti awọn eeyan maa n koju pẹlu wọn.

Image copyright Getty Images

Àwọn ìròyìn mìíràn tí ẹ lè nífẹ̀ẹ́ sí:

Related Topics