Osun Tribunal Judgement: 'Àwa ènìyàn Ọṣun kọ ìdájọ́ tó ní Oyetọla kọ́ ló wọlé sípò gómìnà'

Image copyright Adejare Taofeek

Kẹtikẹti ni awọn olugbe ipinlẹ Ọṣun tu sita lọjọru lati ṣe iwọde tako idajọ igbimọ to sọ pe Sẹnetọ Ademọla Adeleke ti ẹgbẹ osẹlu Peoples Democratic Party lo jawe olubori ninu idibo sipo gomina ipinlẹ naa to waye lọdun 2018.

Image copyright Adejare Taofeek
Àkọlé àwòrán 'Awọn eniyan ipinlẹ Ọṣun kọ idajọ Jankara

Nibi iwọde naa to waye nilu Oṣogbo ni awọn to wọde ti gbe oriṣiriṣi akọle dani lati fi sọ erongba wọn.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAdeleke: Àwọn ará Ẹdẹ bẹ síta pẹ̀lú ìdùnnú lórí ìdájọ́ èsì ìdìbò gómínà Ọṣun
Image copyright Adejare Taofeek
Àkọlé àwòrán 'Oyetọla ni Ọṣun dibo fun.'

Ọjọ Ẹti, ọjọ kejilelogun oṣu Kẹta 2019 ni meji ninu ọmọ igbimọ to gbọ ẹsun to jẹyọ latara idibo naa dajọ pe oludije PDP lo wọle.

Ṣugbọn, o da bi ẹni pe idajọ naa ko ba awọn kan lara mu ni ipinlẹ Ọṣun.

Image copyright Adejare Taofeek
Àkọlé àwòrán 'Ọṣun kọ idajọ ti wọn fi owo ra.'

Iwọde naa ti ẹgbẹ Osun Concerned Citizens ṣe agbatẹru rẹ waye ni ilu Oṣogbo.

Image copyright Adejare Taofeek