Ẹ wo ọmọ ọdún méjì tó ṣeeṣe kò mọ̀wé jù l'ágbàáyé
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Jeremiah Addo: Ọmọ ọdún méjì tó ṣeeṣe kò mọ̀wé jù l'ágbàáyé

Botilẹjẹ wi pe ko fẹsẹ kan ileewe ri, o mọ orukọ ogoji orilẹede ati olu ilu wọn.

Bakan naa lo mọ orukọ awọn aarẹ orilẹede kaakiri agbaye, to fi mọ awọn nkan pataki mi i to n ṣẹlẹ l’agbaye ti ko yẹ ki ọmọ ọdun meji bi tiẹ o mọ.

Baba rẹ, Richard Addo sọ fun BBC pe igba to pe ọmọ ọdun kan ati osṣu mẹẹrin lawọn ti ṣakiyesi pe o tete n mọ nkan. Eyi lo si mu ki wọn o maa kọ ni oriṣiriṣi nkan, ti oun naa si tete n mọ ọ.

‘Koda, ọpọlọ rẹ pe debi wi pe kii gbagbe ohunkohun ti ẹ ba kọ ọ.’’

Ìpanu ‘Cheese ball’ ni wọ́n fi jí Ikimot gbé, àmọ́ ó padà sílé lẹ́yìn ọdún márùn-ún

Yorùbá, ọmọ ọdún mẹ́jọ tà ọmọ òyìnbò yọ nínú ayò Chess l‘Amẹrika

Àwọn àmì tó fi mọ̀ pé wọn ń fipá bá ọmọdébìnrin rẹ lòpọ̀

Akọroyin BBC ṣe idanwo ranpẹ fun lati ọ boya lootọ ni. Iyalẹnu lo si jẹ nigba ti o bẹrẹ si ni i ka oriṣiriṣi nkan.

Baba Jeremiah sọ fun BBC pe nitori pe awọn ko ni owo lọwọ, ọmọ naa ko fi ina mọna-mọna sun ri, tabi wo ẹrọ amohunmaworan ri. Awọn nkan to wa lori ẹrọ ibaraẹnisọrọ alagbeka lo fi n kọ oriṣiriṣi nkan tuntun.

Ẹbi rẹ n kọ ni imọ sayẹnsi ati iṣiro nitori pe wọn ni igbagbs pe yoo dagba, ti yoo si di ilumọọka onimọ sayẹnsi tabi imọ ẹrọ.

Related Topics