BREXIT: Kí ni ohun tó fẹ́ yọ Theresa May nípò olóòtú ìjọba Gẹ̀ẹ́sì ṣáájú àkókò rẹ̀

Theresa May, olotu ijọba ilẹ Gẹẹsi Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Aigbọra ẹni ye lori BREXIT ti n fa ọpọ iwọde ni orilẹede naa.

O ṣeeṣe o ki orilẹede Gẹẹsi o ni olootu ijọba tuntun laipẹ.

Arabinrin Theresa May ni Olootu ijọba ilẹ naa ni lọwọlọwọ yii, saa iṣejọba rẹ ko si tii pari.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Amọṣa, Theresa May ṣeleri pe ni kete ti oun ba ti lee jajabọ lori aba ajọmọ lori adehun ati yẹra ilẹ Gẹẹsi kuro ni awujọ awọn orilẹede Yuroopu, EU, iyẹn BREXIT ti o n lepa rẹ lọwọ, ni onikoyi oun yoo lọ simi ogun.

Igba meji ọtọọtọ ni aba adehun iyapa naa ti ba ijakulẹ pade ni ile aṣofin ilẹ Gẹẹsi.

May yoo tun gbiyanju fun igba kẹta ni ọjọbọ lati tun rọ awọn aṣofin orilẹede naa lati tẹwọ gba aba adehun naa lẹyin to ti jẹ ẹjẹ ati fi ipo silẹ.

Image copyright Getty Images

Nibi ipade kan pẹlu awọn aṣofin ẹgbẹ oṣelu Conservative party to waye ni May ti ṣalaye pe 'Mo ṣetan lati fi ipo yii silẹ ṣaaju asiko to yẹ lọna ati lee ṣe ohun to ba tọ fun orilẹedee wa.

Ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu kẹta ọdun 2019 lo yẹ ki ilẹ Gẹẹsi of fi aaarin awujọ ilẹ Yuroopu, EU silẹ ṣugbọn nitori awọn aigbọraẹniye ti o n waye laaarin awọn adari orilẹede naa lori rẹ,ajọ EU ti fun wọn di ọjọ kejila oṣu kẹrin lati fi tun ile wọn to.