Fashọla: Àwọn ọmọ Nàìjíríà sọ̀rọ̀ lórí ìpèsè iná ọba tí mínísítà Fashọla ní ó ti ń ṣe dédé

Ibudo ina ọba kan Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Kii ṣe iroyin mọ pe ina ọba ko ṣe e mu yangan ni orilẹede Naijiria

Ṣe awọn agba bọ, wọn ni ẹyin lohun, bi o ba ti jabọ ko tun ṣee ko mọ.

Lẹyin ti o ti sọrọ lori eto mohunmaworan abẹle kan lorilẹede Naijiria pe ọpọ ipinlẹ lorilẹede Naijiria ni wọn ti n ni ina ọba fun bii wakati mẹrinlelogun bayii lojumọ, ẹnu o si lẹyin minisita fun ipese ina ọba lorilẹ€de Naijiria, Raji Fashọla.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọpọ ọmọ Naijiria ni wọn ti n pariwo lori oju opo ayelujara, ero wọn lori ọrọ naa. Ko kere ninu awọn ọmọ orilẹede Naijiria ti o n pariwo pe ọrọ to jinna si otitọ ni minisita Fashọla sọ yii, bẹẹni ko ṣai si awọn miran ti wọn sọ pe o fẹ jọ bẹẹ lootọ.

Orilẹede Naijiria wa lara awọn orilẹede ti ina ọba rẹ ko fẹẹ ṣe dede to lagbaye, eleyi ti o si ti gba ọpọ ọrọ abuku laaarin awọn ọmọ orilẹede Naijiria ati loke okun.

Lara awọn to ti fi ohun silẹ lori rẹ ni Sẹnetọ Shehu Sani. Sẹnetọ Sani ni kii ṣe aye yii ni ipinlẹ kan yoo ti maa lo ina ọba fun wakati mẹrinlelogun.

Sẹnetọ naa to n ṣoju ipinlẹ Kano lọwọ bayii, ṣalaye lori opo twitter rẹ pe "awọn ipinlẹ ti o ti lee gbadun ina fun wakati mẹrinlelogun lojumọ ni Uranus, Venus, Mars, Saturn ati Neptune."

Bakan naa ni awọn ọmọ orilẹede yii miran naa ti n bu ẹnu atẹ lu minisita naa. Bi awọn kan ṣe n pariwo pe 'irọ ni o pa'ati pe 'ko yee pa iru iru irọ bẹẹ' ni awọn miran tilẹ n sọ pe 'ko darukọ awọn ipinlẹ naa to ba daa loju.'

Ni oju opo Facebook BBC News Yoruba, awọn eeyan kan lu minisita naa lọgọ ẹnu, wọn si tun kin ọrọ rẹ lẹyin bẹẹ ni awọn miran tun bu ẹnu atẹ lu rọ yii.