Manchester United: Gunnar Solskjaer di akónimọ̀ọ́gbá tuntun

Gunnar Solskjaer Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Gunnar Solskjaer ti jáwé olúborí ìfẹsẹ́wọnsẹ̀ eré bọ́ọ̀lù márìnlá nínú mọ́kàndínlógún láti ìgbà tí ó ti jẹ́ adelé fún osù mẹ́rin.

Ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United ti fi ontẹ lu Ole Gunnar Solskjaer gẹgẹ bi akọnimọọgba tuntun fun ọdun mẹta.

Ole Gunnar Solskjaer ti ti jawe olubori ifẹsẹwọnsẹ ere bọọlu mẹrinla ninu mọkandinlogun lati igba ti o ti jẹ adele fun osu mẹrin.

Osu Kejila, ọdun to kọja ni ọmọ ọdun mẹrindinlaadọta naa pada wa si Man United lati gba isẹ lọwọ Jose Mourinho gẹgẹ bi akọnimọọgba.

Manchester United wa ni ipo kẹrin bayii ninu idije Premier League, ti wọn yoo si ma a koju Barcelona ni ifẹsẹwọnsẹ keji to kangun si asekagba idije UEFA Champions League, lẹyin ti wọn fagba han PSG pẹlu ayo meji ni Paris.

Bakan naa ni Ole Gunnar Solskjaer ni atilẹyin awọn agbabọọlu Man United tẹlẹri, ati awọn to wa nibẹ lọwọlọwọ.

Ti a ko ba gbagbe, saa mọkanla ni Ole Gunnar Solskjaer fi jẹ agbabọọlu Manchester United to si jẹ ẹni to gba bọọlu wọnu awọn ni ọdun 1999 ti wọn fi gba ami ẹyẹ Champions League ti ọdun naa.