Ekiti election appeal: Ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn dá Fayẹmi láàre lórí ẹjọ́ Ẹlẹka

Kayode Fayemi Image copyright @ekitistategov
Àkọlé àwòrán Ẹlẹka pe ẹjọ kotẹmilọrun lẹyin to fi idi rẹmi ni ile ẹjọ akọkọ ni oṣu kini ọdun 2019

Ile ẹjọ to n gbọ ẹjọ kotẹmilọrun ti gbe idajọ kalẹ pe Kayọde Fayẹmi gan an ni oludije ti ilu fi ibo yan sipo gomina ni ipinlẹ Ekiti.

Idajọ yii waye lẹyin ti ile ẹjọ to n gbọ awuye abajade esi idibo gomina nipinlẹ Ekiti gbe kalẹ ṣaaju pe Fayẹmi lo wọle gẹgẹ bii gomina nitootọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ile ẹjọ naa ni ẹjọ kotẹmilọrun ti oludije ẹgbẹ oṣelu PDP, Ọjọgbọn Oluṣọla Ẹlẹka gbe wa si iwaju rẹ ko munadoko to.

Ajọ eleto idibo, INEC ti kede Fayẹmi ati ẹgbẹ oṣelu rẹ, APC gẹgẹ bii olubori ibo gomina ipinlẹ Ekiti pẹlu ibo 197, 459 lati bori Ẹlẹka to ṣe ipo keji pẹlu ibo 178,121.

Fayẹmi bori ni ijọba ibilẹ mejila ninu mẹrindinlogun to wa ni ipinlẹ naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionKí ni àmì ohùn 'Aguntaṣọọlo'?

INEC ni Fayẹmi bori lawọn ijọba ibilẹ Ilejemeje, Irepodun/Ifelodun, Ido/Osi, Oye, Moba, Ijero, Gbonyin, Ekiti West, Ikole, Ise/Orun, Ekiti East ati Ekiti Southwest.

Eẹẹka si bori ni Ado, Ikere, Emure and Efon.