Bola Tinubu Colloquium: Tinubu kìlọ̀ fún Buhari lórí ohun tó leè ṣàkóbá fún sáà kejì rẹ̀

Osinbajo ati Tinubu Image copyright @batcolloquium
Àkọlé àwòrán Tinubu ni agbekalẹ iṣejọba ti yoo mu ilu dẹrun fun araalu ni ki Buhari ati igbimọ iṣejọba rẹ o mojuto

Eto ipade apero eyi ti awọn ọrọ ṣe fun agba oṣelu to tun jẹ aṣiwaju ẹgbẹ oṣelu APC lorilẹede Naijiria, Bọla Tinubu waye nilu Abuja, ọpọ lo si ti n sọrọ lori awọn koko ọrọ ti agba oṣelu naa ba ijọba atawọn oloṣelu sọ. Eyi lo mu ki BBC News Yoruba o ṣe akojọpọ awọn koko mẹta ti agba oṣelu naa mẹnu le.

Lori ọrọ owo ori sisan lori ọja, VAT.

Image copyright Jubril Gawat
Àkọlé àwòrán Tinubu pe fun Atunto ẹka ipese ina ọba

Laipẹ yii ni iroyin jade pe ijọba apapọ ti n gbero lati fi kun owo ori sisan lori awọn ọja rira ati tita lorilẹede Naijiria. Ọpọ lo n sọ pe inira yoo de ba araalu bi ijọba ba gbe igbesẹ yii lootọ.

Afi bi igba ti Aṣiwaju Tinubu gba ẹnu ọpọ ọmọ orilẹede Naijiria sọrọ lori ọrọ naa. Tinubu rọ ijọba aarẹ Muhammadu Buhari ati igbakeji rẹ, Yẹmi Osinbajọ lati yago ketekete si erongba yoowu to ba nii ṣe pẹlu afikun owo ori ọja, VAT.

"Mo fẹ rọ ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo ati ikọ rẹ lati da igbesẹ yoowu ti wọn ba n gbe lori afikun owo ori ọja, VAT duro, mo bẹ yin. Bi a ba mu adinku ba agbara awọn mẹkunu lati ra nnkan lọja, eyi yoo ṣe idiwọ fun idagbasoke ọrọ aje. Dipo eyi, jẹ ki a fẹ oju awọn eeyan to n san owo ori. Kii ṣe afikun owo ori ni a nilo bayii."

Atunto ẹka ipese ina ọba

Image copyright @MsTyma_
Àkọlé àwòrán Tinubu ni ki Buhari o ṣọra lori ọrọ owo ori sisan lori ọja, VAT

Bọla Tinubu ni ijọba Buhari gbọdọ mojuto ọrọ ipese ina ọba nitori ko si idagbasoke ti o lee de ba orilẹede Naijiria laisi ipese ina ọba.

Awọn aba ati amọran to mu wa fun ṣiṣe labẹ atunto naa ni:

  • Imugboro ipese ina ọba ni ida aadọta ninu ọgọrun (50%) laaarin ọdun mẹrin si asiko yii.

O ni ijọba Buhari gbọdọ ṣiṣẹ takuntakun lati fẹ iye agbara ina to wa fun elo awọn ọmọ orilẹede Naijiria loju sii pẹlu ida aadọta.

"A nilo atunto to pegede ninu ẹka afẹfẹ gaasi lati yee fi wọn ṣofo. A gbọdọ ṣe amulo wọn fun idagbasoke ileeṣẹ lorilẹede Naijiria."

  • Sisọ ẹka ipese ina ọba di ti aladani (Privatisation)
Image copyright @batcolloquium
Àkọlé àwòrán Tinubu tun pe fun imugboro ipese ina ọba ni ida aadọta ninu ọgọrun (50%) laaarin ọdun mẹrin si asiko yii

Tinubu ni asiko to fun Buhari lati gbe igbimọ ọlọpọlọ pipe kalẹ fun tita ẹka ipese ina ọba di aladani.

O ni "ẹgbẹ oṣelu PDP bẹrẹ igbesẹ tita ẹka to n pese ina ọba ṣugbọn wọọn ba aye ẹka to n pin ina ọba jẹ"

O ni ẹka yii kii ṣe fun pinpin sapo awọn eeyan kan lorilẹede Naijiria bikoṣe fun idagbasoke gbogbo ilu.

  • Ijọba gbọdọ fopin si ' biili' owo ina ti ko ba iye ina ti araalu n lo mu.

Bakan naa lo niBuhari gbọdọ wa nnkan ṣe si aṣa gbigbe owo ina ti araalu ko lo wa ka wọn mọle fun sisan.

"Opin ni lati de si aṣa gbigbe owo ina ti araalu ko lo wa ka wọn mọle fun sisan. Ohun atẹyinwa leyi yẹ ko jẹ. Ina ti eeyan ba lo lo yẹ ki wọn mu owo rẹ wa fun un ni sisan.

NEXT level kii ṣe akọmọna ọrọ ẹnu lasan

Image copyright @MBuhari
Àkọlé àwòrán Ko si ẹni to lee sọ boya ijọba Buhari yoo tẹle awọn amọran ko tii di mimọ fun araalu

Lasiko ipolongo idibo ni ọrọ akọmọna yii jade latọdọ ikọ ipolongo aarẹ Buhari gẹgẹ bii iwe akọsilẹ opo afojusun ijọba Buhari fun saa keji.

Lasiko to n sọsọ, Bọla Tinubu ni ọrọ yii kii kan n ṣe ọrọ ipolongo lasan, bikoṣe ilepa ti ẹgbẹ APC gbọdọ mojuto lati da igba ọtun pada fun awọn eeyan orilẹede Naijiria.

O ni ohun ti o kan bayii ni lati rii pe wọn fi gbogbo awọn koko to wa ninu eto naa si iṣe.

Boya ijọba Buhari yoo tẹle awọn amọran ko tii di mimọ fun araalu.