Court of Appeal: Ilé ẹjọ́ ní òfin kò mọ Omo-Agege, Waive gẹ́gẹ́ bíi olùdíje APC ní ìpínlẹ̀ Delta

Sen Omo-Agege Image copyright @OvieOmoAgege
Àkọlé àwòrán Wahala ipinya laaarin awọn igun to wa ni ẹgbẹ oṣelu APC ni ipinlẹ Delta lo ṣokunfa ọrọ igbẹjọ ọhun

Ileẹjọ kotẹmilọrun to fikalẹ si ilu Benin ni ipinlẹ Edo ti wọgile ẹjọ kotẹmilọrun kan ti Sẹnetọ Ovie Omo-Agege ati Ẹniọwọ Francis Waive pe niwaju rẹ lati doju idajọ ile ẹjọ giga apapọ ilu Asaba to wọgile ibo rẹ bolẹ.

Ni idajọ ti ile ẹjọ naa gbe kalẹ ni ọjọ ẹti da ipẹjọ awọn mejeeji nu gẹgẹ bii aasa ti ko ni kaun ninu.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Tinubu ki Buhari nílọ̀ lórí àwọn ohun tó leè ṣàkóbá fún sáà kejì rẹ̀

Fintiri fi ìdí gómìnà ìpínlẹ̀ Adamawa janlẹ̀ nínú ìdìbò gómìnà

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOluwakaponeski ní iṣẹ́ ọmọogun ilẹ̀ Amẹ́ríkà ni òun tẹ́lẹ̀ kí òun tó di aláwàdà

Lati igun ẹgbẹ oṣelu APC to faramọWolii Jones Erue ni Omo-Agege ati Waive ti jade lati jawe olubori ninu idibo sile aṣofin apapọ lọdun 2019 lẹyin ti ile ẹjọ giga apapọ ti kọkọ le Wolii Erue gẹgẹ bii alaga ti ofin mọ.

Onidajọ Toyin Adegoke ninu idajọ rẹ lori ẹjọ ti alaga igun miran ninu ẹgbẹ ṣelu APC ni ipinlẹ Delta, Cyril Ogodo pe kede pe irọ nla ni gbogbo igbesẹ ti Jones Erue ba gbe gẹgẹ bii alaga ẹgbẹ oṣelu APC ati pe ko lẹsẹ nlẹ labẹ ofin.

Ile ẹjọ naa ni Ogodo gan an ni alaga ẹgbẹ oṣelu APC ti ofin mọ ni ipinlẹ Delta.

Amọṣa ni idajọ ti ile ẹjọ kotẹmilọrun gbe kalẹ ni ọjọ ẹti, yatọ si pe ile ẹjọ naa wọgile ẹjọ rẹ, o tun ni ki Sẹnets Omo-Agege ati Waive o san ẹgbẹrun lọna ọọdunrun naira gẹgẹ bii owo gba mabinu.