Adamawa election result: Olùdíje PDP já ipò gómìnà gbà mọ́ gómínà Bindow lọ́wọ́

Fintiri Image copyright @AjammaS
Àkọlé àwòrán INEC kede Ẹgbẹ alatako, APC gẹgẹ bii olubori ibo gomina ipinlẹ Adamawa

Oludije fun ipo gomina ninu ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, Ahmadu Fintiri, ti jawe olubori gẹgẹ bi gomina ipinlẹ Adamawa.

Ajọ eleto idibo INEC, kede ni oru ọjọbọ pe Fintiri lo gbegba oroke , lẹyin atundi ibo to waye ni awọn ijọba ipinlẹ kan nipinlẹ naa.

Fintiri ti fi igba kan jẹ adele gomina ipinlẹ naa nigba kan ri, ni akojọpọ ibo 376,552, lati fi bori gomina ipinlẹ naa lọwọlọwọ, to dije labẹ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, Jibrilla Bindow to ni ibo 336, 386.

Atundi ibo naa waye lẹyin ti ile ẹjọ giga kan fagile ofin to n dena ki ajọ eleto idibo ṣe atundi ibo ni awọn ibudo idibo mẹrinlelogoji nipinlẹ naa.

Ẹgbẹ oṣelu Movement Restoration and Defence of Democracy (MRRD) lo pe ẹjọ tako ajọ INEC lati fopin si atundi ibo nipinlẹ Adamawa.

Ninu eto idibo gomina to waye lọjọ kẹsan oṣu Kẹta, oludije ẹgbẹ PDP, Hammadu Fintiri lewaju pẹlu ibo 32,476, lẹyin to ni akojọpọ ibo 367,471. Gomina Jubrilla Bindow si ni ibo 334,995.