Owanbẹ: Gari Ijẹbu, bọ̀ọ̀lì àtàwọn oúnjẹ lágbo ayẹyẹ 'owanbẹ' báyìí

Iresi inu ewe Image copyright www.eatdrinklagos.com
Àkọlé àwòrán Ayipada ti de ba inawo ṣiṣe bayii

Ayẹyẹ ṣiṣe nilẹ Yoruba jẹ nkan ti o maa n kun fun oriṣiriṣi ipalẹmọ lati rii pe ọjọ naa dun, o si larinrin.

Ipalẹmọ maa n bẹrẹ lati ori aṣọ wiwọ, gbọngan ayẹyẹ, olorin ti yoo kọrin ati ounjẹ jijẹ fun awọn alejo.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionẸwa Agọnyin jẹ aayo ounjẹ Badagry

Ọrọ ounjẹ jijẹ kii ṣe ohun afi ọwọ yẹpẹrẹ mu rara, nitorina ni ọpọ to fẹ ṣe ayẹyẹ ṣe maa n wa awọn alase ounjẹ to mọ iṣẹ lati se awọn ounjẹ fun awọn alejo wọn.

Ounjẹ bi irẹsi loriṣiriṣi, amala, iyan, sẹmo, ati awọn ọbẹ loriṣiriṣi lo maa n peju-pesẹ sibi ayẹyẹ nilẹ Yoruba.

Image copyright www.eatdrinklagos.com
Àkọlé àwòrán Ayipada ti de ba inawo ṣiṣe bayii

Ṣugbọn ṣaa, iyatọ ti n deba bi awọn alayẹyẹ ṣe n pese awọn ounjẹ kan fun awọn alejo wọn.

Aye ti n kuro ni pe ki a n ro amala lati ile oninawo, nibayii, gbọngan tabi ori papa ti ayẹyẹ naa ti n waye ni wọn ti n ro amala bayii, ti awọn alejo yoo si maa jẹ ni gbigbona fẹli-fẹli pẹlu ọbẹ ti wọn ba fẹ.

Image copyright www.eatdrinklagos.com
Àkọlé àwòrán Ayipada ti de ba inawo ṣiṣe bayii

Bakan naa ni aye ti n kuro ni fifi odó ibilẹ gun iyan.

Nibayi, aṣa to n jẹyọ nibi ayẹyẹ ni pe awọn kan maa n gba awọn to ni ẹrọ ti wọn fi n lọ ata lati lọ iṣu iyan. Nibi ti ayẹyẹ ti n waye ni wọn yoo ti se iṣu, ti wọn yoo si fi ẹrọ lọ ọ.

Image copyright www.eatdrinklagos.com
Àkọlé àwòrán Ayipada ti de ba inawo ṣiṣe bayii

Wọn yoo si maa bu u fun awọn to ba nifẹ si iyan ni gbigbona.

Lara asa ounjẹ to tun ti n jẹyọ nibi ayẹyẹ bayii ni pe awọn kan ti n fi Gaari Ijẹbu pẹlu omi tutu ati ẹja tabi ẹran adiyẹ dindin ṣe alejo.

Image copyright www.eatdrinklagos.com
Àkọlé àwòrán Ayipada ti de ba inawo ṣiṣe bayii

Laipẹ yii ni gbaju-gbaja olorin Fuji, Wasiu Ayinde Marshal fi fidio kan sita loju opo ayelujara Instagram rẹ. Fidio naa safihan Ayinde nibi to ti n mu gari Ijẹbu pẹlu ẹja dindin ati ede nibi ayẹyẹ igbeyawo kan nilu Ijẹbu Ode.

Olorin fuji naa n mu gari naa tidunnu-tidunnu. Koda, o sọ pe nkan iwuri ni ayipada to n deba awọn ounjẹ ti wọn n pin fun alejo nibi ayẹyẹ.

Bọọli ati ẹja tabi ẹran adiyẹ ti wọn yi lata naa ti n peju-pesẹ sibi ayẹyẹ bayii.

Image copyright boliandgrills
Àkọlé àwòrán Ayipada ti de ba inawo ṣiṣe bayii

Oriṣiriṣi awuyewuye lo n waye lori iru awọn ounjẹ 'tuntun' yi. Awọn kan gbagbọ pe ifiyajẹra ẹni ni ki eniyan fi ile rẹ silẹ lọ sibi ayẹyẹ, ki wọn o wa fun ni ounjẹ bi gari ati ẹja dindin.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Kò sí oúnjẹ Nàìjá tí a ò sè ní Kenya'

Ṣugbọn awọn kan gbagbọ pe awọn ounjẹ pẹẹpẹpẹ naa jẹ ọna lati ṣọ owo na, tabi ṣe nkan to yatọ si ti atijọ.

Niti amala ati iyan gigun nibi ayẹyẹ, awọn kan gbagbọ pe eyi jẹ igbesẹ lati dena bi awọn alejo kan ṣe maa n fi ounjẹ ṣofo.

Related Topics