Ekiti election appeal: Ìpèníjà ráńpẹ́ ni èsì ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn jẹ́ fún wa -PDP

Ojogbon Olusola Eleeka Image copyright @solaeleeka
Àkọlé àwòrán Anfaani ile ẹjọ giga lo ṣẹku fun ọgbẹni Olusola Ẹlẹka lati tako esi ibo Gomina ipinlẹ Ekiti

Ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party nipinlẹ Ekiti ti fesi pe ''ipenija ranpẹ'' ni esi ile ẹjọ kotẹmilọrun to fagile ẹjọ ti oludije wọn ninu idibo gomina, Olusola Eleka gbe wa si iwaju rẹ.

Alaga ẹgbẹ naa, Alagba Gboyega Oguntuase lo sọ ọrọ yi ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu akọroyin ile iṣẹ BBC.

Oguntuase ni ''bi nnkan o ba ku,ki n jinde,Eleka yoo jinde pada bi Lasaru inu Bibeli.''

''Ta lo mọ wi pe PDP le gba Bauchi, ta lo mọ wi pe PDP le gba Benue,ta lomọ wi pe PDP le gba Imo? Agbara Ọlọrun ni yẹn''

O fi kun pe ipenija agbara Ọlọrun ọga ogo ni ohun to n ṣẹlẹ si Ẹlẹka ti yoo si pada bori.

Lọjọbọ ni ile ẹjọ kotẹmilọrun nilu Abuja fidi idajọ mulẹ pe Kayode Fayẹmi ti ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress lo gbegba oroke ninu idibo gomina ipinlẹ naa.

Idajọ naa f'ọwọ rọ ẹjọ ti ọgbẹni Olusọla Eleka ti ẹgbẹ PDP gbe wa si iwaju rẹ pe ko fẹsẹ rinlẹ.

Ninu ọrọ tirẹ, oluranlọwọ fun Olusola Ẹlẹka, Ọgbẹni Felix Olusola sọ pe ẹjọ ti wọn da ni ile ẹjọ akọkọ ati ẹkeji ni bakan ninu.

O fesi yi ni idahun si ibeere BBC nipa esi ile ẹjọ kotẹmilọrun ni orukọ ọga rẹ,Olusola Ẹlẹka.

Olusola ni awọn ti pinu lati tẹsiwaju lọ si ile ẹjọ to ga ju ni Naijiria lati ri pe Olusola Eleka gba ẹtọ rẹ pada.

''Awa ni igbagbọ ninu ẹka eto idajọ Naijiria ,awọn kan ṣi wa nibẹ ti wọn jẹ olootọ.Ti a ba de ile ẹjọ giga pẹlu awọn ẹri ti a ni, a o ri ade to daju''

Nipa boya awọn agbẹjọro wọn ti bẹrẹ igbesẹ lati tẹsiwaju lọ si ile ẹjọ giga, o sọ pe''Laipẹ yi ni wọn yoo bẹrẹ igbesẹ wọn''

Àwọn afíkun lórí ìròyìn yìí